Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 8:8 - Bibeli Mimọ

8 Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si rú soke, o si so eso ọrọrun. Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o nahùn wipe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ dáradára, ó dàgbà, ó sì so èso. Irúgbìn kọ̀ọ̀kan so ọgọọgọrun-un.” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó wá tún sọ pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Òmíràn sì bọ́ sí ilẹ̀ rere, ó sì hù sókè, ó sì so èso ọ̀rọ̀ọ̀rún ju èyí ti a gbin lọ.” Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí tán, ó pariwo sókè pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 8:8
25 Iomraidhean Croise  

Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.


Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun kì yio farapa ninu ikú keji.


Ẹniti o ba li etí ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun ni emi o fi eso igi ìye nì fun jẹ, ti mbẹ larin Paradise Ọlọrun.


Awọn wọnyi si li eyi ti a fún si ilẹ rere; irú awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti wọn si gbà a, ti wọn si so eso, omiran ọgbọgbọ̀n, omiran ọgọtọta, omiran ọgọrọrun.


Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, ti o ndagba ti o si npọ̀; o si mu eso jade wá, omiran ọgbọgbọn, omiran ọgọtọta, omiran ọgọrọ̀run.


Ṣugbọn ẹniti o gbà irugbin si ilẹ rere li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si yé e; on li o si so eso pẹlu, o si so omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.


Eti igbọ́ ati oju irí, Oluwa li o ti dá awọn mejeji.


Ṣugbọn ti ilẹ rere li awọn, ti nwọn fi ọkàn otitọ ati rere gbọ ọrọ na, nwọn di i mu ṣinṣin, nwọn si fi sũru so eso.


Ẹ gbọ́, ki ẹ si fi eti silẹ; ẹ má ṣe gberaga: nitori ti Oluwa ti sọ̀rọ.


ỌGBỌ́N kò ha nkigbe bi? Oye kò ha gbé ohùn rẹ̀ soke bi?


Nigbana ni Isaaki funrugbìn ni ilẹ na, o si ri ọrọrún mu li ọdún na; OLUWA si busi i fun u:


Ki ẹ le mã rìn ni yiyẹ niti Oluwa si ìwu gbogbo, ki ẹ ma so eso ninu iṣẹ rere gbogbo, ki ẹ si mã pọ si i ninu ìmọ Ọlọrun;


Nitori awa ni iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ ti a ti dá ninu Kristi Jesu fun iṣẹ rere, ti Ọlọrun ti pèse tẹlẹ, ki awa ki o le mã rìn ninu wọn.


Oluwa si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli si nyin, o ndide ni kutukutu lati rán wọn, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i, bẹ̃ni ẹnyin kò tẹ eti nyin silẹ lati gbọ́.


Bi ẹnikẹni ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.


Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.


Omiran si bọ́ sinu ẹgún; ẹgún si ba a rú soke, o si fun u pa.


Kò yẹ fun ilẹ, bẽni kò yẹ fun àtan; bikoṣepe ki a kó o danù. Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́ ki o gbọ́.


Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ.


Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ.


Bi ẹnikẹni ba li etí ki o gbọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan