Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 5:8 - Bibeli Mimọ

8 Nigbati Simoni Peteru si ri i, o wolẹ lẹba ẽkun Jesu, o wipe, Lọ kuro lọdọ mi; nitori ẹlẹṣẹ ni mi, Oluwa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Nígbà tí Simoni Peteru rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó ní “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Oluwa.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 5:8
19 Iomraidhean Croise  

Dafidi si bẹru Oluwa ni ijọ na, o si wipe, Apoti-ẹri Oluwa yio ti ṣe tọ̀ mi wá?


On si wi fun Elijah pe, Kili o ṣe mi ṣe ọ, Iwọ enia Ọlọrun? iwọ ha tọ̀ mi wá lati mu ẹ̀ṣẹ mi wá si iranti, ati lati pa mi li ọmọ?


Kiyesi i, ẹgbin li emi; ohùn kili emi o da? emi o fi ọwọ mi le ẹnu mi.


Nwọn si wi fun Mose pe, Iwọ ma bá wa sọ̀rọ̀, awa o si gbọ́: ṣugbọn máṣe jẹ ki Ọlọrun ki o bá wa sọ̀rọ, ki awa ki o má ba kú.


Nigbana ni mo wipe, Egbe ni fun mi, nitori mo gbé, nitoriti mo jẹ́ ẹni alaimọ́ etè, mo si wà lãrin awọn enia alaimọ́ etè, nitoriti oju mi ti ri Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun.


Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́, nwọn da oju wọn bolẹ, ẹru si bà wọn gidigidi.


Nigbati nwọn si wọ̀ ile, nwọn ri ọmọ-ọwọ na pẹlu Maria iya rẹ̀, nwọn wolẹ, nwọn si foribalẹ fun u: nigbati nwọn si tú iṣura wọn, nwọn ta a lọrẹ wura, ati turari, ati ojia.


Balogun ọrún na dahùn, o si wipe, Oluwa, emi ko yẹ ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi; ṣugbọn sọ kìki ọ̀rọ kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada.


Nwọn si ṣapẹrẹ si ẹgbẹ wọn, ti o wà li ọkọ̀ keji, ki nwọn ki o wá ràn wọn lọwọ. Nwọn si wá, nwọn si kún ọkọ̀ mejeji, bẹ̃ni nwọn bẹ̀rẹ si irì.


Hà si ṣe e, ati gbogbo awọn ti mbẹ pẹlu rẹ̀, fun akopọ̀ ẹja ti nwọn kó:


Nigbati Maria si de ibiti Jesu gbé wà, ti o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o wi fun u pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kò ba má kú.


Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji; ṣugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ̀ li apakan; ṣugbọn nigbana li emi ó mọ̀ gẹgẹ bi mo si ti di mimọ̀ pẹlu.


Nigbati mo ri i, mo wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ bi ẹniti o kú. O si fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ le mi, o nwi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru; Emi ni ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin:


Manoa si wi fun aya rẹ̀ pe, Kikú li awa o kú yi, nitoriti awa ti ri Ọlọrun.


Awọn ọkunrin Betṣemeṣi si wipe, Tani yio le duro niwaju Oluwa Ọlọrun mimọ́ yi? ati lọdọ tani yio lọ bi o kuro lọdọ wa?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan