Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 5:1 - Bibeli Mimọ

1 O si ṣe, nigbati ijọ enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti o si duro leti adagun Genesareti,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní àkókò kan, bí Jesu ti dúró létí òkun Genesarẹti, ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Genesareti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 5:1
21 Iomraidhean Croise  

Ki opinlẹ na ki o si ti Ṣefamu sọkalẹ lọ si Ribla, ni ìha ìla-õrùn Aini; ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ, ki o si dé ìha okun Kinnereti ni ìha ìla-õrùn.


Lati igba ọjọ Johanu Baptisti wá, titi o fi di isisiyi ni ijọba ọrun di ifi agbara wọ, awọn alagbara si fi ipá gbà a.


Nigbati nwọn si rekọja si apakeji, nwọn de ilẹ awọn ara Genesareti.


O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn mu ọkọ̀ kekere kan sunmọ on, nitori ijọ enia, ki nwọn ki o má bà bilù u.


O si tún bẹ̀rẹ si ikọni leti okun: ọ̀pọ ijọ enia si pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o bọ́ sinu ọkọ̀ kan, o si joko ninu okun; gbogbo awọn enia si wà ni ilẹ leti okun.


O si ba a lọ; ọ̀pọ enia si ntọ̀ ọ lẹhin, nwọn si nhá a li àye.


Nigbati nwọn si rekọja tan, nwọn de ilẹ awọn ara Genesareti, nwọn si sunmọ eti ilẹ.


O si ṣe, nigbati ainiye ijọ enia pejọ pọ̀, tobẹ̃ ti nwọn ntẹ̀ ara wọn mọlẹ, o tètekọ́ wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ mã ṣọra nyin nitori iwukara awọn Farisi, ti iṣe agabagebe.


O ri ọkọ̀ meji ti nwọn gún leti adagun: ṣugbọn awọn apẹja sọkalẹ kuro ninu wọn, nwọn nfọ̀ àwọn wọn.


O si ṣe ni ijọ kan, o si wọ̀ ọkọ̀ kan lọ ti on ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awa ki o rekọja lọ si ìha keji adagun. Nwọn si ṣikọ̀ lọ.


Bi nwọn si ti nlọ, o sùn; iji nla si de, o nfẹ li oju adagun; nwọn si kún fun omi, nwọn si wà ninu ewu.


Nigbati awọn ẹmi èṣu si jade kuro lara ọkunrin na, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tu pũ nwọn si sure lọ si ibi bèbe sinu adagun, nwọn si rì sinu omi.


Jesu si wipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? Nigbati gbogbo wọn sẹ́, Peteru ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wipe, Olukọni, awọn enia nhá ọ li àye, nwọn si mbilù ọ, iwọ si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi?


Ọkan ninu awọn meji ti o gbọ́ ọ̀rọ Johanu, ti o si tọ̀ Jesu lẹhin, ni Anderu, arakunrin Simoni Peteru.


LẸHIN nkan wọnyi, Jesu kọja si apakeji okun Galili, ti iṣe okun Tiberia.


Pẹtẹlẹ̀ ni pẹlu, ati Jordani ati opinlẹ rẹ̀, lati Kinnereti lọ titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, nisalẹ awọn orisun Pisga ni ìha ìla-õrùn.


Ẹ mã ranti awọn ti nwọn jẹ olori nyin, ti nwọn ti sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun nyin; ki ẹ mã ro opin ìwa-aiye wọn, ki ẹ si mã ṣe afarawe igbagbọ́ wọn.


Ati ni pẹtẹlẹ̀ lọ dé okun Kinnerotu ni ìha ìla-õrùn, ati titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀ ni ìha ìla-õrun, li ọ̀na Beti-jeṣimotu; ati lati gusù lọ nisalẹ ẹsẹ̀-òke Pisga:


Ati ni afonifoji, Beti-haramu, ati Beti-nimra, ati Sukkotu, ati Safoni, iyokù ilẹ-ọba Sihoni ọba Heṣboni, Jordani ati àgbegbe rẹ̀, titi dé ìha opín okun Kinnereti ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan