Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 4:2 - Bibeli Mimọ

2 Ogoji ọjọ li a fi dán a wò lọwọ Èṣu. Kò si jẹ ohunkohun li ọjọ wọnni: nigbati nwọn si pari, lẹhinna li ebi wá npa a.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ogoji ọjọ́ ni èṣù fi dán an wò. Kò jẹ ohunkohun ní gbogbo àkókò náà. Lẹ́yìn náà, ebi wá ń pa á.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 4:2
16 Iomraidhean Croise  

Emi o si fi ọta sãrin iwọ ati obinrin na, ati sãrin irú-ọmọ rẹ ati irú-ọmọ rẹ̀: on o fọ́ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigĩsẹ.


O si dide, o si jẹ, o mu, o si lọ li agbara onjẹ yi li ogoji ọsan ati ogoji oru si Horebu, oke Ọlọrun.


Lọ, pè awọn Ju ti a le ri ni Ṣuṣani jọ, ki ẹnyin si ma gbãwẹ, fun mi, ki ẹnyin ki o máṣe jẹun, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe mu ni ijọ mẹta t'ọsan t'oru: emi pẹlu ati awọn iranṣẹbinrin mi yio gbãwẹ bẹ̃ gẹgẹ; bẹ̃li emi o si wọ̀ ile tọ̀ ọba lọ, ti o lòdi si ofin; bi mo ba ṣègbe, mo ṣègbe.


Mose si lọ sãrin awọsanma na, o sì gùn ori òke na: Mose si wà lori òke li ogoji ọsán ati ogoji oru.


On si wà nibẹ̀, lọdọ OLUWA li ogoji ọsán ati ogoji oru: on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi. On si kọwe ọ̀rọ majẹmu na, ofin mẹwa nì, sara walã wọnni.


O si kede rẹ̀, o si wi pe ki a là Ninefe ja nipa aṣẹ ọba, ati awọn agbagbà rẹ̀ pe, Máṣe jẹ ki enia, tabi ẹranko, ọwọ-ẹran tabi agbo-ẹran, tọ́ ohunkohun wò: má jẹ ki wọn jẹun, má jẹ ki wọn mu omi.


Nigbati o di owurọ̀, bi o ti npada bọ̀ si Jerusalemu, ebi npa a.


Nigbati o si ti gbàwẹ li ogoji ọsán ati ogoji oru, lẹhinna ni ebi npa a.


Eṣu si wi fun u pe, Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ fun okuta yi ki o di akara.


Kanga Jakọbu si wà nibẹ̀. Nitorina bi o ti rẹ̀ Jesu tan nitori ìrin rẹ̀, bẹ̀li o joko leti kanga: o si jẹ ìwọn wakati kẹfa ọjọ.


Emi si wolẹ niwaju OLUWA bi ti iṣaju, li ogoji ọsán ati ogoji oru; emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni emi kò mu omi; nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin ti ẹnyin ṣẹ̀, ni ṣiṣe buburu li oju OLUWA, lati mu u binu.


Mo si wolẹ niwaju OLUWA li ogoji ọsán ati li ogoji oru, bi mo ti wolẹ niṣaju; nitoriti OLUWA wipe, on o run nyin.


Nigbati mo gòke lọ sori òke lati gbà walã okuta wọnni, ani walã majẹmu nì ti OLUWA bá nyin dá, nigbana mo gbé ogoji ọsán, ati ogoji oru lori òke na, emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃li emi kò mu omi.


Nitori niwọnbi on tikararẹ̀ ti jiya nipa idanwo, o le ràn awọn ti a ndan wo lọwọ.


Nitori a kò ni olori alufa ti kò le ṣai ba ni kẹdun ninu ailera wa, ẹniti a ti danwo li ọna gbogbo gẹgẹ bi awa, ṣugbọn lailẹ̀ṣẹ.


Filistini na a si ma sunmọ itosi li owurọ ati li alẹ, on si fi ara rẹ̀ han li ogoji ọjọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan