Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 3:7 - Bibeli Mimọ

7 Nigbana li o wi fun ọ̀pọ awọn enia ti o wá lati baptisi lọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin iran paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Johanu ń sọ fún àwọn eniyan tí ó jáde lọ ṣe ìrìbọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 3:7
12 Iomraidhean Croise  

Emi o si fi ọta sãrin iwọ ati obinrin na, ati sãrin irú-ọmọ rẹ ati irú-ọmọ rẹ̀: on o fọ́ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigĩsẹ.


Nwọn npa ẹyin pamọlẹ, nwọn nhun okùn alantakùn: ẹniti o jẹ ninu ẹyin wọn yio kú, ati eyi ti a tẹ̀ bẹ́ ọká jade.


Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin ti iṣe enia buburu yio ti ṣe le sọ̀rọ rere? nitori ninu ọ̀pọlọpọ ohun inu li ẹnu isọ.


Ẹnyin ejò, ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin o ti ṣe yọ ninu ẹbi ọrun apadi?


A si mbaptisi wọn lọdọ rẹ̀ ni odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn.


Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹ ṣe. Apania li on iṣe lati atetekọṣe, ko si duro ni otitọ; nitoriti kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigbati o ba nṣeke, ninu ohun tirẹ̀ li o nsọ, nitori eke ni, ati baba eke.


Iwọ ti o kún fun arekereke gbogbo, ati fun iwà-ìka gbogbo, iwọ ọmọ Eṣu, iwọ ọta ododo gbogbo, iwọ kì yio ha dẹkun ati ma yi ọna titọ́ Oluwa po?


Ati lati duro dè Ọmọ rẹ̀ lati ọrun wá, ẹniti o si ji dide kuro ninu okú, ani Jesu na, ẹniti ngbà wa kuro ninu ibinu ti mbọ̀.


Pe, nipa ohun aileyipada meji, ninu eyiti ko le ṣe iṣe fun Ọlọrun lati ṣeke, ki awa ti o ti sá sabẹ ãbo le ni ìṣírí ti o daju lati dì ireti ti a gbé kalẹ niwaju wa mu:


Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni; nitori lati àtetekọṣe ni Èṣu ti ndẹṣẹ. Nitori eyi li Ọmọ Ọlọrun ṣe farahàn, ki o le pa iṣẹ Èṣu run.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan