Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 3:5 - Bibeli Mimọ

5 Gbogbo ọgbún li a o kún, gbogbo òke nla ati òke kekere li a o tẹ-bẹrẹ; wíwọ li a o ṣe ni títọ, ati ọ̀na palapala li a o sọ di kikuna;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Gbogbo ọ̀gbun ni yóo jẹ́ dídí gbogbo òkè gíga ati òkè kéékèèké ni yóo jẹ́ rírẹ̀ sílẹ̀. A óo tọ́ ibi tí ó bá ṣe kọ́rọ-kọ̀rọ, a óo sì sọ ọ̀nà tí kò bá dán tẹ́lẹ̀ di dídán

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ; Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́, àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 3:5
11 Iomraidhean Croise  

Gbogbo afonifoji ni a o gbe soke, gbogbo òke-nla ati òke kékèké ni a o si rẹ̀ silẹ: wiwọ́ ni a o si ṣe ni titọ́, ati ọ̀na pàlapala ni a o sọ di titẹ́ju:


Emi o si mu awọn afọju bá ọ̀na ti nwọn kò mọ̀ wá; emi o tọ́ wọn ninu ipa ti wọn kò ti mọ̀; emi o sọ okùnkun di imọlẹ niwaju wọn, ati ohun wiwọ́ di titọ. Nkan wọnyi li emi o ṣe fun wọn, emi kì yio si kọ̀ wọn silẹ.


Emi o lọ siwaju rẹ, emi o si sọ ibi wiwọ́ wọnni di titọ́: emi o fọ ilẹkùn idẹ wọnni tũtũ, emi o si ke ọjá-irin si meji.


Emi o si sọ gbogbo awọn òke-nla mi wọnni di ọ̀na, a o si gbe ọ̀na opopo mi wọnni ga.


Gbogbo igi inu igbẹ ni yio si mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti mu igi giga walẹ, ti mo ti gbe igi rirẹlẹ soke, ti mo ti mu igi tutù gbẹ, ti mo si ti mu igi gbigbẹ ruwé: emi Oluwa li o ti sọ ti mo si ti ṣe e.


Ṣugbọn jẹ ki arakunrin ti iṣe talaka mã ṣogo ni ipo giga rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan