Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 3:11 - Bibeli Mimọ

11 O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li ẹ̀wu meji, ki o fi ọkan fun ẹniti kò ni; ẹniti o ba si li onjẹ, ki o ṣe bẹ̃ pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó bá ní dàńṣíkí meji, kí ó fún ẹni tí kò ní lọ́kan. Ẹni tí ó bá ní oúnjẹ níláti ṣe bákan náà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 3:11
22 Iomraidhean Croise  

Ti kò si ni ẹnikan lara, ṣugbọn ti o ti fi ohun ògo onigbèse fun u, ti kò fi agbara kó ẹnikẹni, ti o ti fi onjẹ rẹ̀ fun ẹniti ebi npa, ti o si ti fi ẹwu bo ẹni-ihoho.


Nitorina ọba, jẹ ki ìmọran mi ki o jẹ itẹwọgba lọdọ rẹ, ki o si fi ododo ja ẹ̀ṣẹ rẹ kuro, ati aiṣedẽde rẹ nipa fifi ãnu hàn fun awọn talaka; bi yio le mu alafia rẹ pẹ.


Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi.


Ki ẹnyin ki o kuku mã ṣe itọrẹ ãnu ninu ohun ti ẹnyin ni; si kiyesi i, ohun gbogbo li o di mimọ́ fun nyin.


Nigbati Jesu si gbọ́ eyi, o wi fun u pe, Ohun kan li o kù fun ọ sibẹ: lọ ità ohun gbogbo ti o ni, ki o si pín i fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá, ki o mã tọ̀ mi lẹhin.


Sakeu si dide, o si wi fun Oluwa pe, Wo o, Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fifun talakà; bi mo ba si fi ẹ̀sun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin.


Nitori awọn miran ninu wọn rò pe, nitori Judasi li o ni àpo, ni Jesu fi wi fun u pe, Rà nkan wọnni ti a kò le ṣe alaini fun ajọ na; tabi ki o le fi nkan fun awọn talakà.


Olufọkansìn, ati ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹniti o nṣe itọrẹ-ãnu pipọ fun awọn enia, ti o si ngbadura sọdọ Ọlọrun nigbagbogbo.


O si wipe, Korneliu, a gbọ́ adura rẹ, ọrẹ-ãnu rẹ si wà ni iranti niwaju Ọlọrun.


Nigbati o si tẹjumọ́ ọ, ti ẹ̀ru si ba a, o ni, Kini, Oluwa? O si wi fun u pe, Adura rẹ ati ọrẹ-ãnu rẹ ti goke lọ iwaju Ọlọrun fun iranti.


Ki ẹniti njale máṣe jale mọ́: ṣugbọn ki o kuku mã ṣe lãlã, ki o mã fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki on ki o le ni lati pín fun ẹniti o ṣe alaini.


Kìlọ fun awọn ti o lọrọ̀ li aiye isisiyi, ki nwọn máṣe gberaga, bẹni ki nwọn máṣe gbẹkẹle ọrọ̀ aidaniloju, bikoṣe le Ọlọrun alãye, ti nfi ohun gbogbo fun wa lọpọlọpọ lati lo;


Ki nwọn ki o mã ṣõre, ki nwọn ki o mã pọ̀ ni iṣẹ rere, ki nwọn mura lati pin funni, ki nwọn ki o ni ẹmi ibakẹdun;


Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀, nipa iṣẹ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe fun awọn enia mimọ́, ti ẹ si nṣe.


Ìsin mimọ́ ati ailẽri niwaju Ọlọrun ati Baba li eyi, lati mã bojutó awọn alainibaba ati awọn opó ninu ipọnju wọn, ati lati pa ara rẹ̀ mọ́ lailabawọn kuro li aiyé.


Ere kili o jẹ, ará mi, bi ẹnikan wipe on ni igbagbọ́, ṣugbọn ti kò ni iṣẹ? igbagbọ́ nì le gbà a là bi?


Ṣugbọn ẹniti o ba ni ohun ini aiye, ti o si ri arakunrin rẹ̀ ti iṣe alaini, ti o si sé ilẹkun ìyọ́nu rẹ̀ mọ ọ, bawo ni ifẹ Ọlọrun ti ngbé inu rẹ̀?


Bi ẹnikẹni ba wipe, Emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rẹ̀, eke ni: nitori ẹniti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on kò ri?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan