Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 3:1 - Bibeli Mimọ

1 LI ọdún kẹdogun ijọba Tiberiu Kesari, nigbati Pontiu Pilatu jẹ Bãlẹ, Judea, ti Herodu si jẹ tetrarki Galili, Filippi arakunrin rẹ̀ si jẹ tetrarki Iturea ati ti Trakoniti, Lisania si jẹ tetrarki Abilene,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní ọdún kẹẹdogun tí Ọba Tiberiu ti wà lórí oyè, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ gomina Judia, tí Hẹrọdu jẹ́ baálẹ̀ Galili, tí Filipi arakunrin rẹ̀ jẹ́ baálẹ̀ Ituria ati ti agbègbè Tirakoniti, Lusaniu jẹ́ baálẹ̀ Abilene;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 3:1
19 Iomraidhean Croise  

Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀.


LI akokò na ni Herodu tetrarki gbọ́ okikí Jesu,


Herodu sá ti mu Johanu, o dè e, o si fi i sinu tubu, nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀.


Ṣugbọn nigbati a nṣe iranti ọjọ ibí Herodu, ọmọbinrin Herodia jó lãrin wọn, inu Herodu si dùn.


Njẹ wi fun wa, Iwọ ti rò o si? Ó tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi ko tọ́?


Nigbati nwọn si dè e tan, nwọn mu u lọ, nwọn si fi i le Pontiu Pilatu lọwọ ti iṣe Bãlẹ.


Herodu tikararẹ̀ sá ti ranṣẹ mu Johanu, o si dè e sinu tubu nitori Herodia, aya Filippi arakunrin rẹ̀: on sá ti fi i ṣe aya.


Nigbati ọjọ ti o wọ̀ si de, ti Herodu sàse ọjọ ibí rẹ̀ fun awọn ijoye rẹ̀, awọn balogun, ati awọn olori ni Galili;


Ni wakati kanna diẹ ninu awọn Farisi tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Jade, ki iwọ ki o si lọ kuro nihinyi: nitori Herodu nfẹ pa ọ.


O SI ṣe li ọjọ wọnni, aṣẹ ti ọdọ Kesari Augustu jade wá pe, ki a kọ orukọ gbogbo aiye sinu iwe.


Pilatu si fi aṣẹ si i pe, ki o ri bi nwọn ti nfẹ.


Ṣugbọn Herodu tetrarki, ti o bawi nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀, ati nitori ohun buburu gbogbo ti Herodu ti ṣe,


Herodu tetrarki si gbọ́ nkan gbogbo ti nṣe lati ọdọ rẹ̀ wá: o si damu, nitoriti awọn ẹlomiran nwipe, Johanu li o jinde kuro ninu okú;


Klaudiu Lisia si Feliksi bãlẹ ọlọla julọ, alafia.


Ṣugbọn lẹhin ọdún meji, Porkiu Festu rọpò Feliksi: Feliksi si nfẹ ṣe oju're fun awọn Ju, o fi Paulu silẹ li ondè.


Nigbati o si sọ nkan wọnyi tan, ọba dide, ati bãlẹ, ati Bernike, ati awọn ti o ba wọn joko:


Nitõtọ sá ni, si Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ ti fi oróro yàn, ati Herodu, ati Pontiu Pilatu, pẹlu awọn keferi, ati awọn enia Israeli pejọ si,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan