Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 23:3 - Bibeli Mimọ

3 Pilatu si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li ọba awọn Ju? O si da a lohùn wipe, Iwọ wi i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Pilatu bá bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?” Ó dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí i.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Pilatu sì bi í léèrè, wí pé, “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù?” Ó sì dá a lóhùn wí pé, “Ìwọ wí i.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 23:3
14 Iomraidhean Croise  

Jesu si duro niwaju Bãlẹ: Bãlẹ si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li Ọba awọn Ju? Jesu si wi fun u pe, Iwọ wi i.


Nwọn si bẹ̀rẹ si ikí i, wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju!


Pilatu si bi i lẽre, wipe Iwọ ha li Ọba awọn Ju? O si dahùn wi fun u pe, Iwọ wi i.


Jẹ ki Kristi, Ọba Israeli, sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, ki awa ki o le ri i, ki a si le gbagbọ́. Awọn ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nkẹgan rẹ̀.


Gbogbo wọn si wipe, Iwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọrun bi? O si wi fun wọn pe, Ẹnyin wipe, emi ni.


Nwọn si kọwe akọlé si ìgbèri rẹ̀ ni ède Hellene, ati ti Latini, ati ti Heberu, EYI LI ỌBA AWỌN JU.


Natanaeli dahùn, o si wi fun u pe, Rabbi, iwọ li Ọmọ Ọlọrun; iwọ li Ọba Israeli.


Nitorina Pilatu jade tọ̀ wọn lọ, o si wipe, Ẹ̀sun kili ẹnyin mu wá si ọkunrin yi?


Nwọn si wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! nwọn si fi ọwọ́ wọn gbá a loju.


Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ti nsọ ohun gbogbo di ãye, ati niwaju Jesu Kristi, ẹni, niwaju Pontiu Pilatu, ti o jẹri ijẹwọ rere,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan