Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 23:2 - Bibeli Mimọ

2 Nwọn si bẹ̀rẹ si ifi i sùn, wipe, Awa ri ọkunrin yi o nyi orilẹ-ede wa li ọkàn pada, o si nda wọn lẹkun lati san owode fun Kesari, o nwipe on tikara-on ni Kristi ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án pé, “A rí i pé ńṣe ni ọkunrin yìí ń ba ìlú jẹ́. Ó ní kí àwọn eniyan má san owó-orí. Ó tún pe ara rẹ̀ ní Mesaya, Ọba.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, “Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó òde fún Kesari, ó ń wí pé, òun tìkára òun ni Kristi ọba.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 23:2
33 Iomraidhean Croise  

O si ṣe, bi Ahabu ti ri Elijah, Ahabu si wi fun u pe, Iwọ li ẹniti nyọ Israeli li ẹnu!


Awọn ẹlẹri eke dide; nwọn mbi mi li ohun ti emi kò mọ̀.


Kiki ìro wọn ni lati já a tilẹ kuro ninu ọlá rẹ̀: nwọn nṣe inu didùn ninu eke: nwọn nfi ẹnu wọn sure, ṣugbọn nwọn ngegun ni inu wọn.


Nitoriti mo gbọ́ ẹgan ọ̀pọlọpọ, idãmu niha gbogbo, nwọn wipe: fi sùn, awa o si fi sùn. Gbogbo awọn ọrẹ mi, ati gbogbo awọn ẹgbẹ mi wipe: bọya a o tãn jẹ, awa o si ṣẹgun rẹ̀, a o si gbẹsan wa lara rẹ̀.


Awọn ijoye si sọ fun ọba pe, Jẹ ki a pa ọkunrin yi: nitori bayi li o mu ọwọ awọn ologun ti o kù ni ilu yi rọ, pẹlu ọwọ gbogbo enia, ni sisọ iru ọ̀rọ bayi fun wọn: nitori ọkunrin yi kò wá alafia awọn enia yi, bikoṣe ibi wọn.


Nigbana ni Amasiah, alufa Beteli ranṣẹ si Jeroboamu ọba Israeli, wipe, Amosi ti ditẹ̀ si ọ lãrin ile Israeli: ilẹ kò si le gba gbogbo ọ̀rọ rẹ̀.


Oluṣọ agutan mẹta ni mo si ke kuro li oṣu kan; ọkàn mi si korira wọn, ọkàn wọn pẹlu si korira mi.


Ṣugbọn ki a má bã bí wọn ninu, iwọ lọ si okun, ki o si sọ ìwọ si omi, ki o si mu ẹja ti o ba kọ́ fà soke; nigbati iwọ ba si yà a li ẹnu, iwọ o ri ṣekeli kan nibẹ̀: on ni ki o mu, ki o si fifun wọn fun temi ati tirẹ.


Nwọn wi fun u pe, Ti Kesari ni. Nigbana li o wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.


Jesu si duro niwaju Bãlẹ: Bãlẹ si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li Ọba awọn Ju? Jesu si wi fun u pe, Iwọ wi i.


Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Ẹnu si yà wọn si i gidigidi.


Pilatu si bi i lẽre, wipe Iwọ ha li Ọba awọn Ju? O si dahùn wi fun u pe, Iwọ wi i.


O sọ fun wọn pe, Ẹnyin mu ọkunrin yi tọ̀ mi wá, bi ẹni ti o npa awọn enia li ọkàn dà: si kiyesi i, emi wadi ẹjọ rẹ̀ niwaju nyin, emi kò si ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi, ni gbogbo nkan wọnyi ti ẹnyin fi i sùn si:


Nwọn si tubọ tẹnumọ ọ pe, O nrú awọn enia soke, o nkọ́ni ká gbogbo Judea, o bẹ̀rẹ lati Galili wá titi o fi de ihinyi.


Nitorina Pilatu jade tọ̀ wọn lọ, o si wipe, Ẹ̀sun kili ẹnyin mu wá si ọkunrin yi?


Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ibamaṣepe ọkunrin yi nhùwa ibi, a kì ba ti fà a le ọ lọwọ.


Nitori eyi Pilatu nwá ọ̀na lati dá a silẹ: ṣugbọn awọn Ju kigbe, wipe, Bi iwọ ba dá ọkunrin yi silẹ, iwọ kì iṣe ọrẹ́ Kesari: ẹnikẹni ti o ba ṣe ara rẹ̀ li ọba, o sọ̀rọ òdi si Kesari.


Bẹ̃ni nwọn kò le ladi ohun ti nwọn fi mi sùn si nisisiyi.


Nitori awa ri ọkunrin yi, o jẹ onijagidi enia, ẹniti o ndá rukerudo silẹ lãrin gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo aiye, ati olori ẹ̀ya awọn Nasarene:


Nitorina ẹ san ohun ti o tọ fun ẹni gbogbo: owo-ode fun ẹniti owo-ode iṣe tirẹ̀: owo-bode fun ẹniti owo-bode iṣe tirẹ̀; ẹ̀ru fun ẹniti ẹ̀ru iṣe tirẹ̀; ọlá fun ẹniti ọlá iṣe tirẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan