Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 21:4 - Bibeli Mimọ

4 Nitori gbogbo awọn wọnyi fi sinu ẹ̀bun Ọlọrun lati ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aìni rẹ̀ o sọ gbogbo ohun ini rẹ̀ ti o ni sinu rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Nítorí gbogbo àwọn yòókù mú ọrẹ wá ninu ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ní; ṣugbọn òun tí ó jẹ́ aláìní, ó mú gbogbo ohun tí ó fi ẹ̀mí tẹ̀ wá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 21:4
7 Iomraidhean Croise  

Nitori gbogbo nwọn sọ sinu rẹ̀ ninu ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aini rẹ̀ o sọ ohun gbogbo ti o ni si i, ani gbogbo ini rẹ̀.


Eyi aburo ninu wọn wi fun baba rẹ̀ pe, Baba, fun mi ni ini rẹ ti o kàn mi. O si pín ohun ìni rẹ̀ fun wọn.


O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, talakà opó yi fi si i jù gbogbo wọn lọ:


Obinrin kan ti o si ni isun ẹ̀jẹ lati igba ọdún mejila, ti o ná ohun gbogbo ti o ni fun awọn oniṣegun, bẹ̃ni a ko le mu u larada lati ọwọ́ ẹnikan wá,


Nitori kò si ẹnikan ninu wọn ti o ṣe alaini: nitori iye awọn ti o ni ilẹ tabi ile tà wọn, nwọn si mu owo ohun ti nwọn tà wá.


Nitori bi imura-tẹlẹ ba wà ṣaju, o jasi itẹwọgbà gẹgẹ bi ohun ti enia bá ni, kì iṣe gẹgẹ bi ohun ti kò ni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan