Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 2:9 - Bibeli Mimọ

9 Sá si kiyesi i, angẹli Oluwa na yọ si wọn, ogo Oluwa si ràn yi wọn ká: ẹ̀ru si ba wọn gidigidi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Angẹli Oluwa kan bá yọ sí wọn, ògo Oluwa tan ìmọ́lẹ̀ yí wọn ká. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 2:9
27 Iomraidhean Croise  

Awọn alufa kò si le duro ṣiṣẹ nitori awọsanma na: nitori ogo Oluwa kún ile Oluwa.


O si ṣe, nigbati Aaroni nsọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si bojuwò ìha ijù, si kiyesi i, ogo OLUWA hàn li awọsanma na.


Ati li owurọ̀ li ẹnyin o si ri ogo OLUWA; nitoriti o gbọ́ kikùn nyin si OLUWA: ta si li awa, ti ẹnyin nkùn si wa?


Ni titanna yio tanna; yio si yọ̀ ani pẹlu ayọ̀ ati orin: ogo Lebanoni li a o fi fun u, ẹwà Karmeli on Ṣaroni; nwọn o ri ogo Oluwa, ati ẹwà Ọlọrun wa.


A o si fi ogo Oluwa hàn, gbogbo ẹran-ara ni yio jùmọ ri i: nitori ẹnu Oluwa li o sọ ọ.


DIDE, tàn imọlẹ: nitori imọlẹ rẹ dé, ogo Oluwa si yọ lara rẹ.


Mo si dide, mo si lọ si pẹtẹlẹ, si kiyesi i ogo Oluwa duro nibẹ, bi ogo ti mo ri lẹba odò Kebari: mo si doju mi bolẹ.


Ṣugbọn nigbati o nrò nkan wọnyi, wò o, angẹli Oluwa yọ si i li oju alá, o wipe, Josefu, iwọ ọmọ Dafidi, má fòiya lati mu Maria aya rẹ si ọdọ; nitori eyi ti o yún ninu rẹ̀, lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ ni.


Angẹli na si tọ̀ ọ wá, o ni, Alãfia iwọ ẹniti a kọjusi ṣe li ore, Oluwa pẹlu rẹ: alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin.


Awọn oluṣọ-agutan mbẹ ni ilu na, nwọn nṣọ agbo agutan wọn li oru ni pápá ti nwọn ngbé.


O si ṣe, bi nwọn ti nṣe rọunrọ̀un kiri niha ibẹ̀, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ didan duro tì wọn:


Nkan wọnyi ni Isaiah wi, nitori o ti ri ogo rẹ̀, o si sọ̀rọ rẹ̀.


Si wo o, angẹli Oluwa duro tì i, imọlẹ si mọ́ ninu tubu: nigbati o si lù Peteru pẹ́pẹ li ẹgbẹ o ji i, o ni, Dide kánkan. Ẹwọn rẹ̀ si bọ́ silẹ kuro lọwọ rẹ̀.


Nitori angẹli Ọlọrun, ti ẹniti emi iṣe, ati ẹniti emi nsìn, o duro tì mi li oru aná,


Ṣugbọn angẹli Oluwa ṣí ilẹkun tubu li oru; nigbati o si mu wọn jade, o wipe,


Ṣugbọn gbogbo wa nwò ogo Oluwa laisi iboju bi ẹnipe ninu awojiji, a si npawada si aworan kanna lati ogo de ogo, ani bi lati ọdọ Oluwa ti iṣe Ẹmí.


Nitori Ọlọrun, ẹniti o wipe ki imọlẹ ki o mọlẹ lati inu òkunkun jade, on li o ti nmọlẹ li ọkàn wa, lati fun wa ni imọlẹ ìmọ ogo Ọlọrun li oju Jesu Kristi.


Laiṣiyemeji, titobi ni ohun ijinlẹ ìwa-bi-Ọlọrun, ẹniti a fihan ninu ara, ti a dalare ninu Ẹmí, ti awọn angẹli ri, ti a wasu rẹ̀ lãrin awọn orilẹ-ede, ti a gbagbọ ninu aiye, ti a gba soke sinu ogo.


Iran na si lẹrù tobẹ̃, ti Mose wipe, ẹ̀ru bà mi gidigidi mo si warìri.


LẸHIN nkan wọnyi mo si ri angẹli miran, o nti ọrun sọkalẹ wá ti on ti agbara nla; ilẹ aiye si ti ipa ogo rẹ̀ mọlẹ.


Mo si ri itẹ́ funfun nla kan, ati ẹni ti o joko lori rẹ̀, niwaju ẹniti aiye ati ọrun fò lọ; a kò si ri ãye fun wọn mọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan