Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 2:7 - Bibeli Mimọ

7 O si bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin, o si fi ọja wé e, o si tẹ́ ẹ sinu ibujẹ ẹran; nitoriti àye kò si fun wọn ninu ile èro.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Ó bá bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkunrin, ó fi ọ̀já wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran, nítorí kò sí àyè fún wọn ninu ilé èrò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí ààyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 2:7
16 Iomraidhean Croise  

Bi ọkan ninu wọn si ti tú àpo rẹ̀ ni ile-èro lati fun kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ li onjẹ, o kofiri owo rẹ̀; si wò o, o wà li ẹnu àpo rẹ̀.


O si ṣe, nigbati awa dé ile-èro, ti awa tú àpo wa, si kiyesi i, owo olukuluku wà li ẹnu àpo rẹ̀, owo wa ni pípe ṣánṣan: awa si tun mú u li ọwọ́ pada wá.


Ṣugbọn kòkoro li emi, kì isi iṣe enia; ẹ̀gan awọn enia, ati ẹlẹya awọn enia.


O si ṣe li ọ̀na ninu ile-èro, li OLUWA pade rẹ̀, o si nwá ọ̀na lati pa a.


Nitorina, Oluwa tikalarẹ̀ yio fun nyin li àmi kan, kiyesi i, Wundia kan yio loyun, yio si bi ọmọkunrin kan, yio si pe orukọ rẹ̀ ni Immanueli.


On ko si mọ̀ ọ titi o fi bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin: o si pè orukọ rẹ̀ ni JESU.


Ọmọ gbẹnagbẹna kọ yi? iya rẹ̀ kọ́ a npè ni Maria? ati awọn arakunrin rẹ̀ kọ́ Jakọbu, Jose, Simoni, ati Juda?


Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, ati awọn ẹiyẹ oju ọrun ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio gbé fi ori rẹ̀ le.


O si tọ̀ ọ lọ, o si dì i lọgbẹ, o da oróro on ọti-waini si i, o si gbé e le ori ẹranko ti on tikalarẹ̀, o si mu u wá si ile-èro, o si nṣe itọju rẹ̀.


O si ṣe, nigbati nwọn wà nibẹ̀, ọjọ rẹ̀ pé ti on o bí.


Awọn oluṣọ-agutan mbẹ ni ilu na, nwọn nṣọ agbo agutan wọn li oru ni pápá ti nwọn ngbé.


Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.


Nitori ẹnyin mọ̀ ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi, pe bi on ti jẹ ọlọrọ̀ rí, ṣugbọn nitori nyin o di talaka, ki a le sọ nyin di ọlọrọ̀ nipa aini rẹ̀.


Ṣugbọn nigbati akokò kíkun na de, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ jade wá, ẹniti a bí ninu obinrin, ti a bi labẹ ofin,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan