Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 2:51 - Bibeli Mimọ

51 O si ba wọn sọkalẹ lọ si Nasareti, o si fi ara balẹ fun wọn: ṣugbọn iya rẹ̀ pa gbogbo nkan wọnyi mọ́ ninu ọkàn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

51 Ó bá bá wọn lọ sí Nasarẹti, ó sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. Ìyá rẹ̀ pa gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi mọ́ ní ọkàn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

51 Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn: ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 2:51
15 Iomraidhean Croise  

Awọn arakunrin rẹ̀ si ṣe ilara rẹ̀; ṣugbọn baba rẹ̀ pa ọ̀rọ na mọ́.


Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ.


Titi de ihinyi li opin ọ̀ran na. Bi o ṣe ti emi Danieli ni, igbero inu mi dãmu mi gidigidi, oju mi si yipada lori mi: ṣugbọn mo pa ọran na mọ́ li ọkàn mi.


Nigbati o nsọ̀rọ wọnyi fun awọn enia, wò o, iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ duro lode, nwọn nfẹ ba a sọ̀rọ.


Jesu si dahùn, o wi fun u pe, Jọwọ rẹ̀ bẹ̃ na: nitori bẹ̃li o yẹ fun wa lati mu gbogbo ododo ṣẹ. Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀.


O si ṣe li ọjọ wọnni, Jesu jade wá lati Nasareti ti Galili, a si ti ọwọ́ Johanu baptisi rẹ̀ li odò Jordani.


Gbẹnagbẹna na kọ yi, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Jose, ati ti Juda, ati Simoni? awọn arabinrin rẹ̀ kò ha si wà nihinyi lọdọ wa? Nwọn si kọsẹ̀ lara rẹ̀.


Nwọn si wi fun u pe, Jesu ti Nasareti li o nkọja lọ.


Ṣugbọn Maria pa gbogbo nkan wọnyi mọ́, o nrò wọn ninu ọkàn rẹ̀.


Nigbati nwọn si ti ṣe nkan gbogbo tan gẹgẹ bi ofin Oluwa, nwọn pada lọ si Galili, si Nasareti ilu wọn.


O si wá si Nasareti, nibiti a gbé ti tọ́ ọ dàgba: bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si wọ̀ inu sinagogu lọ li ọjọ isimi, o si dide lati kàwe.


O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o pa owe yi si mi pe, Oniṣegun, wò ara rẹ sàn: ohunkohun ti awa gbọ́ pe o ti ọwọ́ rẹ ṣe ni Kapernaumu, ṣe e nihinyi pẹlu ni ilẹ ara rẹ.


Ẹ mã tẹriba fun ara nyin ni ìbẹru Ọlọrun.


Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ̀ ipasẹ rẹ̀:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan