Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 2:10 - Bibeli Mimọ

10 Angẹli na si wi fun wọn pe, Má bẹ̀ru: sawò o, mo mu ihinrere ayọ̀ nla fun nyin wá, ti yio ṣe ti enia gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Ṣugbọn angẹli náà wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù mọ́, nítorí mo mú ìròyìn ayọ̀ ńlá fun yín wá, ayọ̀ tí yóo jẹ́ ti gbogbo eniyan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Angẹli náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìhìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 2:10
30 Iomraidhean Croise  

Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré; ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye.


Iwọ onihinrere Sioni, gùn òke giga lọ: Iwọ onihin-rere Jerusalemu, gbé ohùn rẹ soke pẹlu agbara; gbé e soke, má bẹ̀ru; wi fun awọn ilu Juda pe, Ẹ wò Ọlọrun nyin!


Ẹni-ikini o wi fun Sioni pe, Wò o, on na nĩ: emi o fi ẹnikan ti o mú ihinrere wá fun Jerusalemu.


O si wipe, O ṣe ohun kekere ki iwọ ṣe iranṣẹ mi, lati gbe awọn ẹyà Jakobu dide, ati lati mu awọn ipamọ Israeli pada: emi o si fi ọ ṣe imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le ṣe igbala mi titi de opin aiye.


Oluwa ti fi apá mimọ́ rẹ̀ hàn li oju gbogbo awọn orilẹ-ède; gbogbo opin aiye yio si ri igbala Ọlọrun wa.


Ẹsẹ ẹniti o mu ihinrere wá ti dara to lori awọn oke, ti nkede alafia; ti nmu ihìn rere ohun rere wá, ti nkede igbala; ti o wi fun Sioni pe, Ọlọrun rẹ̀ njọba!


ẸMI Oluwa Jehofah mbẹ lara mi: nitori o ti fi ami ororo yàn mi lati wãsu ihin-rere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi lati ṣe awotán awọn onirobinujẹ ọkàn, lati kede idasilẹ fun awọn igbekùn, ati iṣisilẹ tubu fun awọn ondè.


O si wipe, iwọ ọkunrin olufẹ gidigidi, má bẹ̀ru: alafia ni fun ọ, mu ara le. Ani mu ara le, Nigbati on ba mi sọ̀rọ, a si mu mi lara le, mo si wipe, Ki oluwa mi ki o ma sọ̀rọ, nitoriti iwọ ti mu mi lara le.


Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ.


Ṣugbọn lojukanna ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tújuka; Emi ni; ẹ má bẹ̀ru.


Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi.


Angẹli na si dahùn, o si wi fun awọn obinrin na pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitori emi mọ̀ pe ẹnyin nwá Jesu, ti a ti kàn mọ agbelebu.


O si nwipe, Akokò na de, ijọba Ọlọrun si kù si dẹ̀dẹ: ẹ ronupiwada, ki ẹ si gbà ihinrere gbọ́.


O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda.


Ṣugbọn angẹli na wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Sakariah: nitoriti adura rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yio si bí ọmọkunrin kan fun ọ, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Johanu.


Angẹli na si dahùn o wi fun u pe, Emi ni Gabrieli, ti ima duro niwaju Ọlọrun; emi li a rán wá lati sọ fun ọ, ati lati mu ìhin ayọ̀ wọnyi fun ọ wá.


Angẹli na si wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Maria: nitori iwọ ti ri ojurere lọdọ Ọlọrun.


Nitori a bí Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa.


Ati ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹ̀ṣẹ li orukọ rẹ̀, li orilẹ-ède gbogbo, bẹ̀rẹ lati Jerusalemu lọ.


O si ṣe lẹhinna, ti o nlà gbogbo ilu ati iletò lọ, o nwasu, o nrò ìhin ayọ̀ ijọba Ọlọrun: awọn mejila si mbẹ lọdọ rẹ̀.


Awa si mu ihinrere wá fun nyin, ti ileri tí a ti ṣe fun awọn baba,


Nwọn o ha si ti ṣe wasu, bikoṣepe a rán wọn? gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹsẹ awọn ti nwasu ihinrere alafia ti dara to, awọn ti nwãsu ihin ayọ̀ ohun rere!


Fun emi ti o kere ju ẹniti o kere julọ ninu gbogbo awọn enia mimọ́, li a fi ore-ọfẹ yi fun, lati wasu awamáridi ọrọ̀ Kristi fun awọn Keferi;


Bi ẹnyin ba duro ninu igbagbọ́, ti ẹ fẹsẹmulẹ ti ẹ si duro ṣinṣin, ti ẹ kò si yẹsẹ kuro ninu ireti ihinrere ti ẹnyin ti gbọ́, eyiti a si ti wasu rẹ̀ ninu gbogbo ẹda ti mbẹ labẹ ọrun, eyiti a fi emi Paulu ṣe iranṣẹ fun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan