Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 19:4 - Bibeli Mimọ

4 O si sure siwaju, o gùn ori igi sikamore kan, ki o ba le ri i: nitoriti yio kọja lọ niha ibẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Ó bá sáré lọ siwaju, ó gun igi sikamore kan kí ó lè rí i, nítorí ọ̀nà ibẹ̀ ni Jesu yóo gbà kọjá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ó sì súré síwájú, ó gun orí igi sikamore kan, kí ó bà lè rí i: nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 19:4
11 Iomraidhean Croise  

Ọba si ṣe ki fadakà ki o wà ni Jerusalemu bi okuta, ati igi kedari li o ṣe ki o dabi igi sikamore ti mbẹ ni afonifoji fun ọ̀pọlọpọ.


Ati lori igi-olifi, ati igi-sikamore ti mbẹ ni pẹ̀tẹlẹ ni Baal-hanani ara Gederi wà; ati lori iṣura ororo ni Joaṣi wà.


Ọba si ṣe ki fadakà ati wura ki o wà ni Jerusalemu bi okuta, ati igi kedari li o ṣe ki o dabi igi sikamore ti o wà ni afonifoji fun ọ̀pọlọpọ.


Ọba si sọ fadakà dabi okuta ni Jerusalemu, ati igi-kedari li o si ṣe bi sikamore, ti o wà ni pẹtẹlẹ li ọ̀pọlọpọ.


O fi yinyin pa àjara wọn, o si fi yinyin nla pa igi sikamore wọn.


Briki wọnni ṣubu lu ilẹ, ṣugbọn awa o fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: a ke igi sikamore lu ilẹ, ṣugbọn a o fi igi kedari pãrọ wọn.


Nigbana ni Amosi dahùn, o si wi fun Amasiah pe, Emi ki iṣe woli ri, bẹ̃ni emi kì iṣe ọmọ woli, ṣugbọn olùṣọ-agùtan li emi ti iṣe ri, ati ẹniti iti ma ká eso ọpọ̀tọ:


Oluwa si wipe, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irugbin mustardi, ẹnyin o le wi fun igi sikamine yi pe, Ki a fà ọ tú, ki a si gbìn ọ sinu okun; yio si gbọ́ ti nyin.


O si nfẹ lati ri ẹniti Jesu iṣe; kò si le ri i, nitori ọ̀pọ enia, ati nitoriti on ṣe enia kukuru.


Nigbati Jesu si de ibẹ̀, o gbé oju soke, o si ri i, o si wi fun u pe, Sakeu, yara, ki o si sọkalẹ; nitori emi kò le ṣaiwọ ni ile rẹ loni.


Nigbati nwọn kò si ri ọ̀na ti nwọn iba fi gbé e wọle nitori ijọ enia, nwọn gùn oke àja ile lọ, nwọn sọ̀ ọ kalẹ li alafo àja ti on ti akete rẹ̀ larin niwaju Jesu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan