Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 17:3 - Bibeli Mimọ

3 Ẹ mã kiyesara nyin: bi arakunrin rẹ ba ṣẹ̀, ba a wi; bi o ba si ronupiwada, dari jì i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ẹ ṣọ́ra yín! “Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, bá a wí; bí ó bá ronupiwada, dáríjì í.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ẹ máa kíyèsára yín. “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 17:3
18 Iomraidhean Croise  

Jẹ ki olododo ki o lù mi; iṣeun ni yio jasi: jẹ ki o si ba mi wi; ororo daradara ni yio jasi, ti kì yio fọ́ mi lori: sibẹ adura mi yio sa wà nitori jamba wọn.


Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o má ba bá awọn ara ilẹ na dá majẹmu, nibikibi ti iwọ nlọ, ki o má ba di idẹwò fun ọ lãrin rẹ:


Ibawi wọ̀ inu ọlọgbọ́n jù ọgọrun paṣan lọ ninu aṣiwère.


Ibawi nigbangba, o san jù ifẹ ti o farasin lọ.


Máṣe ba ẹlẹgàn wi, ki o má ba korira rẹ, ba ọlọgbọ́n enia wi, yio si ma fẹ ọ.


Iwọ kò gbọdọ korira arakunrin rẹ li ọkàn rẹ: ki iwọ ki o bá ẹnikeji rẹ wi, ki iwọ ki o máṣe jẹbi nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.


Nigbana ni Peteru tọ̀ ọ wá, o wipe, Oluwa, nigba melo li arakunrin mi yio ṣẹ̀ mi, ti emi o si fijì i? titi di igba meje?


Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin, ki ọkàn nyin ki o máṣe kún fun wọ̀bia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan aiye yi, ti ọjọ na yio si fi de ba nyin lojijì bi ikẹkun.


Nitorina ẹ kiyesi lati mã rìn ni ìwa pipé, kì iṣe bi awọn alailọgbọn, ṣugbọn bi awọn ọlọgbọn;


Nitorina ki ẹnyin ki o ma kiyesara nyin gidigidi, nitoripe ẹnyin kò ri apẹrẹ kan li ọjọ́ ti OLUWA bá nyin sọ̀rọ ni Horebu lati ãrin iná wá:


Ẹ ma ṣọra nyin, ki ẹnyin má ba gbagbé majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti o ti bá nyin dá, ki ẹnyin má ba lọ ṣe ere finfin fun ara nyin, tabi aworán ohunkohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti kọ̀ fun ọ.


Kìki ki iwọ ki o ma kiyesara rẹ, ki o si ṣọ́ ọkàn rẹ gidigidi, ki iwọ ki o má ba gbagbé ohun ti oju rẹ ti ri, ati ki nwọn ki o má ba lọ kuro li àiya rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ṣugbọn ki iwọ ki o ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ;


Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe kùna ore-ọfẹ Ọlọrun; ki gbòngbo ikorò kan ki o má ba hù soke ki o si yọ nyin lẹnu, ọ̀pọlọpọ a si ti ipa rẹ̀ di aimọ́;


Ará, bi ẹnikẹni ninu nyin ba ṣìna kuro ninu otitọ, ti ẹnikan si yi i pada;


Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ère kíkún gbà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan