Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 16:2 - Bibeli Mimọ

2 Nigbati o si pè e, o wi fun u pe, Ẽṣe ti emi fi ngbọ́ eyi si ọ? siro iṣẹ iriju rẹ; nitori iwọ ko le ṣe iriju mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ọ̀gá rẹ̀ bá pè é, ó sọ fún un pé, ‘Irú ìròyìn wo ni mò ń gbọ́ nípa rẹ yìí? Ṣírò iṣẹ́ rẹ bí ọmọ-ọ̀dọ̀, nítorí n óo dá ọ dúró lẹ́nu iṣẹ́.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? Ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mi mọ́.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 16:2
23 Iomraidhean Croise  

Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu.


Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ.


Nigbati o di oju alẹ oluwa ọgba ajara wi fun iriju rẹ̀ pe, Pè awọn alagbaṣe nì, ki o si fi owo agbaṣe wọn fun wọn, bẹ̀rẹ lati ẹni ikẹhin lọ si ti iṣaju.


Ṣugbọn Ọlọrun wi fun u pe, Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ?


Oluwa si dahùn wipe, Tani olõtọ ati ọlọ́gbọn iriju na, ti oluwa rẹ̀ fi jẹ olori agbo ile rẹ̀, lati ma fi ìwọn onjẹ wọn fun wọn li akokò?


O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu pe, Ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o ni iriju kan; on na ni nwọn fi sùn u pe, o ti nfi ohun-ini rẹ̀ ṣòfo.


Iriju na si wi ninu ara rẹ̀ pe, Ewo li emi o ṣe? nitoriti Oluwa mi gbà iṣẹ iriju lọwọ mi: emi kò le wàlẹ; lati ṣagbe oju ntì mi.


Njẹ nitorina, olukuluku wa ni yio jihin ara rẹ̀ fun Ọlọrun.


Nitori a ti fihàn mi nipa tinyin, ará mi, lati ọdọ awọn ara ile Kloe, pe ìja mbẹ larin nyin.


Pẹlupẹlu a mbere lọwọ iriju pe ki oluwarẹ̀ na ki o jẹ olõtọ.


Nitorina, ẹ máṣe ṣe idajọ ohunkohun ṣaju akokò na, titi Oluwa yio fi de, ẹniti yio mu ohun òkunkun ti o farasin wá si imọlẹ, ti yio si fi ìmọ ọkàn hàn: nigbana li olukuluku yio si ni iyìn tirẹ̀ lọdọ Ọlọrun.


Nitoripe gbogbo wa kò le ṣaima fi ara hàn niwaju itẹ́ idajọ Kristi; ki olukuluku ki o le gbà nkan wọnni ti o ṣe ninu ara, gẹgẹ bi eyi ti o ti ṣe, ibã ṣe rere ibã ṣe buburu.


Máṣe ainani ẹ̀bun ti mbẹ lara rẹ, eyiti a fi fun ọ nipa isọtẹlẹ pẹlu ifọwọle awọn àgba.


Ẹ̀ṣẹ awọn ẹlomiran a mã han gbangba, a mã lọ ṣãju si idajọ; ti awọn ẹlomiran pẹlu a si mã tẹle wọn.


Bi olukuluku ti ri ẹ̀bun gbà, bẹ̃ni ki ẹ mã ṣe ipinfunni rẹ̀ larin ara nyin, bi iriju rere ti onirũru ore-ọfẹ Ọlọrun.


Awọn ẹniti yio jihin fun ẹniti o mura ati ṣe idajọ ãye on okú.


Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣí awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe ìye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan