Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 13:7 - Bibeli Mimọ

7 O si wi fun oluṣọgba rẹ̀ pe, Sawõ, lati ọdún mẹta li emi ti nwá iwò eso lori igi ọpọtọ yi, emi ko si ri nkan: ké e lulẹ; ẽṣe ti o fi ngbilẹ lasan pẹlu?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Ó wá sọ fún olùtọ́jú ọgbà pé, ‘Ṣé o rí i! Ó di ọdún mẹta tí mo ti ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí tí n kò rí. Gé e lulẹ̀. Kí ló dé tí yóo kàn máa gbilẹ̀ lásán?’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ó sì wí fún olùṣọ́gbà rẹ̀ pé, ‘Sá à wò ó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan: ké e lulẹ̀; èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú?’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 13:7
11 Iomraidhean Croise  

Njẹ nisisiyi jọwọ mi jẹ, ki ibinu mi ki o gbona si wọn, ki emi ki o le pa wọn run: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla.


O kigbe li ohùn rara, o si wi bayi pe, Ke igi na lulẹ, ki o si ke awọn ẹka rẹ̀ kuro, gbọ̀n ewe rẹ̀ danu; ki o si fọn eso rẹ̀ ka, jẹ ki awọn ẹranko igbẹ kuro labẹ rẹ̀, ki awọn ẹiyẹ si kuro lori ẹka rẹ̀:


Ati nigbati ẹnyin o ba si dé ilẹ na, ti ẹnyin o si gbìn onirũru igi fun onjẹ, nigbana ni ki ẹnyin kà eso rẹ̀ si alaikọlà: li ọdún mẹta ni ki o jasi bi alaikọlà fun nyin; ki a máṣe jẹ ẹ.


Nigbana li emi o fi aṣẹ ibukún mi fun nyin li ọdún kẹfa, on o si so eso jade fun nyin fun ọdún mẹta.


Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ké e lùlẹ, a si wọ́ ọ sọ sinu iná.


O si dahùn o wi fun u pe, Oluwa, jọwọ rẹ̀ li ọdún yi pẹlu, titi emi o fi tú ilẹ idi rẹ̀ yiká, titi emi o si fi bu ilẹdu si i:


Ati nisisiyi pẹlu, a fi ãke le gbòngbo igi na: gbogbo igi ti kò ba so eso rere, a ke e lulẹ, a si wọ́ ọ jù sinu iná.


Gbogbo ẹká ninu mi ti kò ba so eso, on a mu u kuro: gbogbo ẹka ti o ba si so eso, on a wẹ̀ ẹ mọ́, ki o le so eso si i.


Bi ẹnikan kò ba gbé inu mi, a gbe e sọnu gẹgẹ bi ẹka, a si gbẹ; nwọn a si kó wọn jọ, nwọn a si sọ wọn sinu iná, nwọn a si jóna.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan