Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 13:2 - Bibeli Mimọ

2 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣebi awọn ara Galili wọnyi ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn ara Galili lọ, nitoriti nwọn jẹ irú ìya bawọnni?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ rò pé àwọn ará Galili wọnyi jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo ará Galili yòókù lọ ni, tí wọ́n fi jẹ irú ìyà yìí?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Galili wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Galili lọ, nítorí wọ́n jẹ irú ìyà bá-wọ̀n-ọn-nì?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 13:2
6 Iomraidhean Croise  

AWỌN kan si wà li akokò na ti o sọ ti awọn ara Galili fun u, ẹ̀jẹ ẹniti Pilatu dàpọ mọ ẹbọ wọn.


Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ.


Tabi awọn mejidilogun, ti ile-iṣọ ni Siloamu wólu, ti o si pa wọn, ẹnyin ṣebi nwọn ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn enia ti mbẹ̀ ni Jerusalemu lọ?


Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe. Olukọni, tani dẹṣẹ, ọkunrin yi tabi awọn obi rẹ̀, ti a fi bi i li afọju?


Bi awọn alaigbede na si ti ri ẹranko oloró na ti dì mọ́ ọ li ọwọ́, nwọn ba ara wọn sọ pe, Dajudaju apania li ọkunrin yi, ẹniti o yọ ninu okun tan, ṣugbọn ti ẹsan kò si jẹ ki o wà lãye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan