Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 13:13 - Bibeli Mimọ

13 O si fi ọwọ́ rẹ̀ le e: lojukanna a si ti sọ ọ di titọ, o si nyìn Ọlọrun logo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Jesu bá gbé ọwọ́ mejeeji lé e. Lẹsẹkẹsẹ ni ẹ̀yìn rẹ̀ bá nà, ó bá ń fi ògo fún Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé e: Lójúkan náà a sì ti sọ ọ́ di títọ́, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 13:13
13 Iomraidhean Croise  

Nigbati ijọ enia si rí i, ẹnu yà wọn, nwọn yìn Ọlọrun logo, ti o fi irú agbara bayi fun enia.


Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, kì yio pa wọn lara rara: nwọn o gbé ọwọ́ le awọn ọlọkunrun, ara wọn ó da.


O si bẹ̀ ẹ gidigidi, wipe, Ọmọbinrin mi kekere wà loju ikú: mo bẹ̀ ọ ki o wá fi ọwọ́ rẹ le e, ki a le mu u larada: on o si yè.


On ko si le ṣe iṣẹ agbara kan nibẹ̀, jù pe o gbé ọwọ́ rẹ̀ le awọn alaisan diẹ, o si mu wọn larada.


Lẹhin eyini o si tún fi ọwọ́ kàn a loju, o si mu ki o wòke: o si sàn, o si ri gbogbo enia gbangba.


Nigbati Jesu ri i, o pè e si ọdọ, o si wi fun u pe, Obinrin yi, a tú ọ silẹ lọwọ ailera rẹ.


Lojukanna o si riran, o si ntọ̀ ọ lẹhin, o nyìn Ọlọrun logo: ati gbogbo enia nigbati nwọn ri i, nwọn fi iyìn fun Ọlọrun.


Nigbati õrùn si nwọ̀, gbogbo awọn ẹniti o ni olokunrun ti o li arunkarun, nwọn mu wọn tọ̀ ọ wá; o si fi ọwọ́ le olukuluku wọn, o si mu wọn larada.


Anania si lọ, o si wọ̀ ile na; nigbati o si fi ọwọ́ rẹ̀ le e, o ni, Saulu Arakunrin, Oluwa li o rán mi, Jesu ti o fi ara hàn ọ li ọ̀na ti iwọ ba wá, ki iwọ ki o le riran, ki o si kún fun Ẹmí Mimọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan