Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 12:2 - Bibeli Mimọ

2 Kò si ohun ti a bò, ti a kì yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ṣugbọn kò sí ohun kan tí a fi aṣọ bò tí a kò ní ṣí aṣọ lórí rẹ̀. Kò sì sí ohun àṣírí tí eniyan kò ní mọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 12:2
10 Iomraidhean Croise  

Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu.


Nitoriti oju mi mbẹ lara ọ̀na wọn gbogbo: nwọn kò pamọ kuro niwaju mi, bẹ̃ni ẹ̀ṣẹ wọn kò farasin kuro li oju mi.


Nwọn rubọ ẹran ninu ẹbọ ẹran mi, nwọn si jẹ ẹ; Oluwa kò tẹwọgbà wọn; nisisiyi ni yio ránti ìwa-buburu wọn, yio si bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò: nwọn o padà lọ si Egipti.


Nitori kò si ohun ti o pamọ́ bikoṣe ki a le fi i hàn; bẹ̃ni kò si ohun ti o wà ni ikọkọ, bikoṣepe ki o le yọ si gbangba.


Nitori kò si ohun ti o lumọ́, ti a ki yio fi hàn, bẹ̃ni kò si ohun ti o pamọ́, ti a kì yio mọ̀, ti ki yio si yọ si gbangba.


Li ọjọ na nigbati Ọlọrun yio ti ipa Jesu Kristi ṣe idajọ aṣiri enia gẹgẹ bi ihinrere mi.


Nitorina, ẹ máṣe ṣe idajọ ohunkohun ṣaju akokò na, titi Oluwa yio fi de, ẹniti yio mu ohun òkunkun ti o farasin wá si imọlẹ, ti yio si fi ìmọ ọkàn hàn: nigbana li olukuluku yio si ni iyìn tirẹ̀ lọdọ Ọlọrun.


Nitoripe gbogbo wa kò le ṣaima fi ara hàn niwaju itẹ́ idajọ Kristi; ki olukuluku ki o le gbà nkan wọnni ti o ṣe ninu ara, gẹgẹ bi eyi ti o ti ṣe, ibã ṣe rere ibã ṣe buburu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan