Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 10:2 - Bibeli Mimọ

2 O si wi fun wọn pe, Ikore pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan: nitorina ẹ bẹ̀ Oluwa ikore, ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikore rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ó sọ fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí ó tó kórè pọ̀ ninu oko, ṣugbọn àwọn òṣìṣẹ́ kò pọ̀ tó. Nítorí náà, ẹ bẹ Oluwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sí ibi ìkórè rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 10:2
48 Iomraidhean Croise  

Elijah si wi fun awọn enia na pe, Emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù ni woli Oluwa; ṣugbọn awọn woli Baali ãdọta-lenirinwo ọkunrin,


Oluwa ti sọ̀rọ: ọ̀pọlọpọ si li ogun awọn ẹniti nfi ayọ̀ rohin rẹ̀:


Emi o si fun nyin li oluṣọ-agutan gẹgẹ bi ti inu mi, ti yio fi ìmọ ati oye bọ́ nyin.


Egbe ni fun oluṣọ agutan asan na ti o fi ọwọ́-ẹran silẹ! idà yio wà li apá rẹ̀, ati li oju ọ̀tun rẹ̀: apá rẹ̀ yio gbẹ patapata, oju ọ̀tun rẹ̀ yio si ṣõkùnkun biribiri.


Ti awọn oluwa wọn npa wọn, ti nwọn kò si kà ara wọn si pe nwọn jẹbi: ati awọn ti ntà wọn wipe, Ibukún ni fun Oluwa, nitoriti mo di ọlọrọ̀: awọn oluṣọ agutan wọn kò si ṣãnu wọn.


Emi o si sọkalẹ wá, emi o si bá ọ sọ̀rọ nibẹ̀: emi o si mú ninu ẹmi ti mbẹ lara rẹ, emi o si fi i sara wọn; nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù awọn enia na, ki iwọ ki o máṣe nikan rù u.


Mose si wi fun u pe, Iwọ njowú nitori mi? gbogbo enia OLUWA iba le jẹ́ wolĩ, ki OLUWA ki o fi ẹmi rẹ̀ si wọn lara!


IJỌBA ọrun sá dabi ọkunrin kan ti iṣe bãle ile, ti o jade ni kutukutu owurọ lati pè awọn alagbaṣe sinu ọgba ajara rẹ̀.


Nitori Ọmọ-enia dabi ọkunrin kan ti o lọ si àjo ti o jìna rére, ẹniti o fi ile rẹ̀ silẹ, ti o si fi aṣẹ fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iṣẹ olukuluku fun u, ti o si fi aṣẹ fun oluṣọna ki o mã ṣọna.


O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda.


Nwọn si jade lọ, nwọn si nwasu nibigbogbo, Oluwa si mba wọn ṣiṣẹ, o si nfi idi ọ̀rọ na kalẹ, nipa àmi ti ntẹ̀le e. Amin.


O si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejila jọ, o si fun wọn li agbara on aṣẹ lori awọn ẹmi èṣu gbogbo, ati lati wò arùn sàn.


Nitorina awọn ti a si tuka kiri niti inunibini ti o ṣẹ̀ niti Stefanu, nwọn rìn titi de Fenike, ati Kipru, ati Antioku, nwọn kò sọ ọ̀rọ na fun ẹnikan, bikoṣe fun kìki awọn Ju.


Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́ wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si.


Njẹ bi a ti rán wọn lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ lọ, nwọn sọkalẹ lọ si Seleukia; lati ibẹ̀ nwọn si wọkọ̀ lọ si Kipru.


Ẹ kiyesara nyin, ati si gbogbo agbo ti Ẹmí Mimọ́ fi nyin ṣe alabojuto rẹ̀, lati mã tọju ijọ Ọlọrun, ti o ti fi ẹ̀jẹ ara rẹ̀ rà.


O si wi fun mi pe, Mã lọ: nitori emi ó rán ọ si awọn Keferi lokere réré.


Awọn ti nwọn si túka lọ si ibi gbogbo, nwọn nwasu ọ̀rọ na.


Ọlọrun si gbé awọn miran kalẹ ninu ijọ, ekini awọn aposteli, ekeji awọn woli, ẹkẹta awọn olukọni, lẹhinna iṣẹ iyanu, lẹhinna ẹ̀bun imularada, iranlọwọ, ẹbùn akoso, onirũru ède.


Ṣugbọn nipa õre-ọfẹ Ọlọrun, mo ri bi mo ti ri: õre-ọfẹ rẹ̀ ti a fifun mi kò si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ jù gbogbo wọn lọ: ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe õre-ọfẹ Ọlọrun ti o wà pẹlu mi.


NJẸ bi alabaṣiṣẹpọ pẹlu rẹ̀, awa mbẹ̀ nyin ki ẹ máṣe gbà ore-ọfẹ Ọlọrun lasan.


Nitori gbogbo wọn ni ntọju nkan ti ara wọn, kì iṣe nkan ti iṣe ti Jesu Kristi.


Mo ka a si pe n ko le ṣairan Epafroditu arakunrin mi si nyin, ati olubaṣiṣẹ mi ati ọmọ-ogun ẹgbẹ mi, ṣugbọn iranṣẹ nyin, ati ẹniti nṣe iranṣẹ fun mi ninu aini mi.


Nitoripe nitori iṣẹ Kristi li o ṣe sunmọ ẹnu-ọ̀na ikú, ti kò si kà ẹmí ara rẹ̀ si, lati mu aitó iṣẹ isin nyin si mi kun.


Eyiti emi nṣe lãlã ti mo si njijakadi fun pẹlu, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀, ti nfi agbara ṣiṣẹ gidigidi ninu mi.


Epafra, ẹniti iṣe ọkan ninu nyin, iranṣẹ Kristi, kí nyin, on nfi iwaya-ija gbadura nigbagbogbo fun nyin, ki ẹnyin ki o le duro ni pipé ati ni kíkun ninu gbogbo ifẹ Ọlọrun.


Nitori ẹnyin ranti, ará, ìṣẹ́ ati lãlã wa: nitori awa nṣe lãlã li ọsán ati li oru, ki awa ko má bã di ẹrù ru ẹnikẹni ninu nyin, awa wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin.


Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, lati mã mọ awọn ti nṣe lãla larin nyin, ti nwọn si nṣe olori nyin ninu Oluwa, ti nwọn si nkìlọ fun nyin;


LAKOTAN, ará, ẹ mã gbadura fun wa, ki ọ̀rọ Oluwa le mã sáre, ki o si jẹ ãyìn logo, ani gẹgẹ bi o ti ri lọdọ nyin:


Nitori fun eyi li awa nṣe lãlã ti a si njijakadi, nitori awa ni ireti ninu Ọlọrun alãye, ẹniti iṣe Olugbala gbogbo enia, pẹlupẹlu ti awọn ti o gbagbọ́.


Ṣugbọn mã ṣe pẹlẹ ninu ohun gbogbo, mã farada ipọnju, ṣe iṣẹ efangelisti, ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe.


PAULU, onde Kristi Jesu, ati Timotiu arakunrin wa, si Filemoni olufẹ ati alabaṣiṣẹ wa ọwọn,


Ṣugbọn Kristi bi ọmọ lori ile rẹ̀; ile ẹniti awa iṣe, bi awa ba dì igbẹkẹle ati iṣogo ireti wa mu ṣinṣin titi de opin.


SI angẹli ijọ ni Efesu kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o mu irawọ meje na li ọwọ́ ọtún rẹ̀, ẹniti nrìn li arin ọpá wura fitila meje na wipe,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan