Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 1:6 - Bibeli Mimọ

6 Awọn mejeji si ṣe olododo niwaju Ọlọrun, nwọn nrìn ni gbogbo ofin on ìlana Oluwa li ailẹgan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Àwọn mejeeji ń rìn déédé níwájú Ọlọrun, wọ́n ń pa gbogbo àwọn àṣẹ ati ìlànà Oluwa mọ́ láì kùnà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 1:6
33 Iomraidhean Croise  

NIGBATI Abramu si di ẹni ọkandilọgọrun ọdún, OLUWA farahàn Abramu, o si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare; mã rìn niwaju mi, ki iwọ ki o si pé.


Wọnyi ni ìtan Noa: Noa ṣe olõtọ ati ẹniti o pé li ọjọ́ aiye rẹ̀, Noa mba Ọlọrun rìn.


OLUWA si wi fun Noa pe, iwọ wá, ati gbogbo awọn ara ile rẹ sinu ọkọ̀, nitori iwọ ni mo ri li olododo niwaju mi ni iran yi.


Nitori Dafidi ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, kò si yipada kuro ninu gbogbo eyiti o paṣẹ fun u li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, bikoṣe ni kiki ọ̀ran Uriah, ara Hitti.


Bi iwọ o ba rìn niwaju mi: bi Dafidi baba rẹ ti rìn, ni otitọ ọkàn, ati ni iduroṣinṣin, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo ti pa li aṣẹ fun ọ, ti iwọ o si pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́:


Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, ranti nisisiyi bi emi ti rìn niwaju rẹ ninu otitọ ati ninu aiya pipe, ti mo si ti ṣe eyiti o dara li oju rẹ. Hesekiah si sọkún gidigidi.


Ṣugbọn o wá Ọlọrun baba rẹ̀, o si rìn ninu ofin rẹ̀, ki iṣe bi iṣe Israeli.


ỌKUNRIN kan wà ni ilẹ Usi, orukọ ẹniti ijẹ Jobu; ọkunrin na si ṣe olõtọ, o duro ṣinṣin, ẹniti o si bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu.


Oluwa si sọ fun Satani pe, Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ, ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu.


Emi mọ̀ pe bẹ̃ni nitõtọ! bawo li enia yio ha ti ṣe alare niwaju Ọlọrun?


Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo.


Ṣugbọn nwọn kò li ọmọ, nitoriti Elisabeti yàgan, awọn mejeji si di arugbo.


O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li awọn ti ndare fun ara nyin niwaju enia; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọkàn nyin: nitori eyi ti a gbé niyin lọdọ enia, irira ni niwaju Ọlọrun.


Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ni Jerusalemu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Simeoni; ọkunrin na si ṣe olõtọ ati olufọkànsin, o nreti itunu Israeli: Ẹmí Mimọ́ si bà le e.


Nitori Dafidi ti wi nipa tirẹ̀ pe, Mo ri Oluwa nigba-gbogbo niwaju mi, nitoriti o mbẹ li ọwọ́ ọtún mi, ki a mà bà ṣí mi ni ipò:


NIGBATI Paulu si tẹjumọ igbimọ, o ni, Ará, emi ti nfi gbogbo ẹri-ọkàn rere lò aiye mi niwaju Ọlọrun titi fi di oni yi.


Ninu eyi li emi si nṣe idaraya, lati ni ẹri-ọkàn ti kò li ẹ̀ṣẹ sipa ti Ọlọrun, ati si enia nigbagbogbo.


Iwọ kò ni ipa tabi ipín ninu ọ̀ràn yi: nitori ọkàn rẹ kò ṣe dédé niwaju Ọlọrun.


Ki a le mu ododo ofin ṣẹ ninu awa, ti kò rin nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí.


Njẹ, ará, mo yìn nyin ti ẹnyin nranti mi ninu ohun gbogbo, ti ẹnyin ti di ẹ̀kọ́ wọnni mu ṣinṣin, ani gẹgẹ bi mo ti fi wọn le nyin lọwọ.


Nitori eyi ni iṣogo wa, ẹ̀rí-ọkàn wa, pe, ni iwa-mimọ́ ati ododo Ọlọrun, kì iṣe nipa ọgbọ́n ara, bikoṣe nipa ore-ọfẹ Ọlọrun, li awa nhuwa li aiye, ati si nyin li ọ̀pọlọpọ.


Ki ẹnyin ki o si ma rìn ninu gbogbo ọ̀na ti OLUWA Ọlọrun nyin palaṣẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le yè, ki o si le dara fun nyin, ati ki ẹnyin ki o le mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ ti ẹnyin yio ní.


Ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn ati oniwa tutu, ọmọ Ọlọrun, alailabawọn, larin oniwà wíwọ ati alarekereke orilẹ-ede, larin awọn ẹniti a nri nyin bi imọlẹ li aiye;


Ninu ara rẹ̀ nipa ikú, lati mu nyin wá iwaju rẹ̀ ni mimọ́ ati ailabawọn ati ainibawi;


Ki o ba le fi ọkàn nyin balẹ li ailabukù ninu ìwa mimọ́ niwaju Ọlọrun ati Baba wa, nigba atiwá Jesu Kristi Oluwa wa pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀.


Nitorina, olufẹ, bi ẹnyin ti nreti irú nkan wọnyi, ẹ mura giri, ki a le bá nyin li alafia, li ailabawọn, ati li ailàbuku li oju rẹ̀.


Bi ẹnyin ba mọ̀ pe olododo ni on, ẹ mọ̀ pe a bi olukuluku ẹniti nṣe ododo nipa rẹ̀.


Nipa eyi li a si mọ̀ pe awa mọ̀ ọ, bi awa ba npa ofin rẹ̀ mọ́.


Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o tàn nyin: ẹniti o ba nṣe ododo, o jasi olododo, gẹgẹ bi on ti iṣe olododo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan