Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 1:51 - Bibeli Mimọ

51 O ti fi agbara hàn li apa rẹ̀; o ti tú awọn onirera ká ni ironu ọkàn wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

51 Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fi agbára rẹ̀ hàn, ó tú àwọn tí ó gbéraga ninu ọkàn wọn ká.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

51 Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀; o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 1:51
32 Iomraidhean Croise  

Bẹ̃li OLUWA tú wọn ká lati ibẹ̀ lọ si ori ilẹ gbogbo: nwọn si ṣíwọ ilu ti nwọn ntẹdó.


Ọlọrun si ri pe ìwabuburu enia di pipọ̀ li aiye, ati pe gbogbo ìro ọkàn rẹ̀ kìki ibi ni lojojumọ.


OLUWA si gbọ́ õrun didùn; OLUWA si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ki yio si tun fi ilẹ ré nitori enia mọ́; nitori ìro ọkàn enia ibi ni lati ìgba ewe rẹ̀ wá; bẹ̃li emi ki yio tun kọlù ohun alãye gbogbo mọ́ bi mo ti ṣe.


Ìró ayọ̀ ati ti ìṣẹ́gun mbẹ ninu agọ awọn olododo; ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara.


Oluwa mu ìmọ awọn orilẹ-ède di asan: o mu arekereke awọn enia ṣaki.


Emi o ma yìn ọ lailai nitoripe iwọ li o ṣe e: emi o si ma duro de orukọ rẹ; nitori ti o dara li oju awọn enia mimọ́ rẹ.


Bi ẹnipe ijà ati ọ̀ra bẹ̃ni yio tẹ ọkàn mi lọrun; ẹnu mi yio si ma fi ète ayọ̀ yìn ọ:


Iwọ li o ti ya Rahabu pẹrẹ-pẹrẹ bi ẹniti a pa; iwọ ti fi apa ọwọ́ agbara rẹ tú awọn ọtá rẹ ká.


Iwọ ni apá agbara: agbara li ọwọ́ rẹ, giga li ọwọ ọtún rẹ.


Ẹ kọrin titun si Oluwa; nitoriti o ti ṣe ohun iyanu: ọwọ ọtún rẹ̀, ati apa rẹ̀ mimọ́ li o ti mu igbala wa fun ara rẹ̀.


Mo mọ̀ nisisiyi pe OLUWA tobi jù gbogbo oriṣa lọ: nitõtọ, ninu ọ̀ran ti nwọn ti ṣeféfe si wọn.


Kiyesi i, Oluwa Jehofah yio wá ninu agbara, apá rẹ̀ yio ṣe akoso fun u: kiyesi i, ère rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ si mbẹ niwaju rẹ̀.


Ji, ji, gbe agbara wọ̀, Iwọ apa Oluwa; ji, bi li ọjọ igbãni, ni iran atijọ. Iwọ kọ́ ha ke Rahabu, ti o si ṣá Dragoni li ọgbẹ́?


Oluwa ti fi apá mimọ́ rẹ̀ hàn li oju gbogbo awọn orilẹ-ède; gbogbo opin aiye yio si ri igbala Ọlọrun wa.


Ti o fi ọwọ́ ọtun Mose dà wọn, pẹlu apá rẹ̀ ti o logo, ti o npin omi meji niwaju wọn, lati ṣe orukọ aiyeraiye fun ara rẹ̀?


Nitori, wò o, emi o ṣe ọ ni ẹni-kekere lãrin awọn orilẹ-ède, ẹni-ẹgan lãrin awọn enia.


Nisisiyi, emi Nebukadnessari yìn, mo si gbé Ọba ọrun ga, mo si fi ọlá fun u, ẹniti gbogbo iṣẹ rẹ̀ iṣe otitọ, ati gbogbo ọ̀na rẹ̀ iṣe idajọ: ati awọn ti nrìn ninu igberaga, on le rẹ̀ wọn silẹ.


Nitori igbati nwọn mọ̀ Ọlọrun, nwọn kò yìn i logo bi Ọlọrun, bẹ̃ni nwọn kò si dupẹ; ṣugbọn èro ọkàn wọn di asán, a si mu ọkàn òmúgọ wọn ṣókunkun.


Awa nsọ gbogbo ero kalẹ, ati gbogbo ohun giga ti ngbé ara rẹ̀ ga si ìmọ Ọlọrun, awa si ndi gbogbo ero ni igbekun wá si itẹriba fun Kristi;


Tabi Ọlọrun ha dán a wò rí lati lọ mú orilẹ-ède kan fun ara rẹ̀ lati ãrin orilẹ-ède miran wá, nipa idanwò, nipa àmi, ati nipa iṣẹ-iyanu, ati nipa ogun, ati nipa ọwọ́ agbara, ati nipa ninà apa, ati nipa ẹ̀ru nla, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun nyin ṣe fun nyin ni Egipti ni oju nyin?


Bẹ̃ pẹlu, ẹnyin ipẹ̃rẹ, ẹ tẹriba fun awọn àgba. Ani, gbogbo nyin, ẹ mã tẹriba fun ara nyin, ki ẹ si fi irẹlẹ wọ̀ ara nyin li aṣọ: nitori Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn O nfi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ.


Nitorina ni ijọ kan ni iyọnu rẹ̀ yio de, ikú, ati ibinujẹ, ati ìyan; a o si fi iná sun u patapata: nitoripe alagbara ni Oluwa Ọlọrun ti nṣe idajọ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan