Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 1:3 - Bibeli Mimọ

3 O si yẹ fun mi pẹlu, lati kọwe si ọ lẹsẹsẹ bi mo ti wadi ohun gbogbo kinikini si lati ipilẹsẹ, Teofilu ọlọla jùlọ,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Mo ti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ohun gbogbo fínnífínní. Èmi náà wá pinnu láti kọ ìwé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ, ọlọ́lá jùlọ, Tiofilu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nítorí náà, ó sì yẹ fún èmi pẹ̀lú, láti kọ̀wé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ bí mo ti wádìí ohun gbogbo fínní fínní sí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Teofilu ọlọ́lá jùlọ,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 1:3
17 Iomraidhean Croise  

Oluwa Ọlọrun mi ọ̀pọlọpọ ni iṣẹ iyanu ti iwọ ti nṣe, ati ìro inu rẹ sipa ti wa: a kò le kà wọn fun ọ li ẹsẹ-ẹsẹ: bi emi o wi ti emi o sọ̀rọ wọn, nwọn jù ohun kikà lọ.


Nkan wọnyi ni iwọ ṣe emi si dakẹ; iwọ ṣebi emi tilẹ dabi iru iwọ tikararẹ; emi o ba ọ wi, emi o si kà wọn li ẹsẹ-ẹsẹ ni oju rẹ.


Ki emi ki o le mu ọ mọ̀ idaju ọ̀rọ otitọ; ki iwọ ki o le ma fi idahùn otitọ fun awọn ti o rán ọ?


Ati pẹlu, nitori Oniwasu na gbọ́n, o si nkọ́ awọn enia ni ìmọ pẹlu; nitõtọ o ṣe akiyesi daradara, o si wadi, o si fi owe pupọ lelẹ li ẹsẹsẹ.


NIWỌNBI ọ̀pọ enia ti dawọle e lati tò ìhin wọnni jọ lẹsẹsẹ, eyiti o ti gbilẹ ṣinṣin lãrin wa,


TEOFILU, ìhìn iṣaju ni mo ti rò, niti ohun gbogbo ti Jesu bẹ̀rẹ si iṣe, ati si ikọ́,


Ṣugbọn Peteru bẹ̀rẹ si ilà a fun wọn lẹsẹsẹ, wipe,


Njẹ ìmọràn temi ni, ki a máṣe yọ awọn ti o yipada si Ọlọrun lẹnu ninu awọn Keferi:


O yẹ loju awa, bi awa ti fi imọ ṣọkan lati yàn enia ati lati rán wọn si nyin, pẹlu Barnaba on Paulu awọn olufẹ wa.


Nitori o dara loju Ẹmi Mimọ́, ati loju wa, ki a máṣe dì ẹrù kà nyin, jù nkan ti a ko le ṣe alaiṣe wọnyi lọ:


Nigbati o si gbé ọjọ diẹ nibẹ̀, o lọ, o si kọja ni ilẹ Galatia on Frigia lẹsẹsẹ, o nmu gbogbo awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le.


Klaudiu Lisia si Feliksi bãlẹ ọlọla julọ, alafia.


Nigbagbogbo, ati nibigbogbo, li awa nfi gbogbo ọpẹ́ tẹwọgbà a, Feliksi ọlọla julọ.


Ṣugbọn Paulu wipe, Ori mi kò bajẹ, Festu ọlọlá julọ; ṣugbọn ọ̀rọ otitọ ati ti ìwa airekọja li emi nsọ jade.


Ṣugbọn niti Apollo arakunrin wa, mo bẹ ẹ pupọ ki o tọ̀ nyin wá pẹlu awọn arakunrin: ṣugbọn kì iṣe ifẹ rẹ̀ rara lati wá nisisiyi; ṣugbọn on o wá nigbati o ba ni akokò ti o wọ̀.


Ṣugbọn gẹgẹ bi imọ̀ mi, alabukun-fun julọ ni bi on ba duro bẹ̃: emi pẹlu si rò pe mo li Ẹmi Ọlọrun.


Bi iwọ ba nrán awọn ará leti nkan wọnyi, iwọ o jẹ iranṣẹ rere ti Kristi Jesu, ti a nfi ọrọ igbagbọ́ ati ẹ̀kọ rere bọ́, eyiti iwọ ti ntẹle.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan