Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 9:9 - Bibeli Mimọ

9 Nwọn si wi fun u pe, Ni ilu òkere rére li awọn iranṣẹ rẹ ti wá, nitori orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoriti awa ti gbọ́ okikí rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ṣe ni Egipti,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ọ̀nà jíjìn ni àwa iranṣẹ rẹ ti wá nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, nítorí a ti gbúròó rẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó ṣe sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Wọ́n sì dáhùn pé: “Ní ilẹ̀ òkèèrè ní àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wá, nítorí orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Ejibiti,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 9:9
21 Iomraidhean Croise  

Pẹlupẹlu, niti alejò, ti kì iṣe ti inu Israeli enia rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ okerè jade wá nitori orukọ rẹ.


Awọn ọmọ Lefi, Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣabaiah, Ṣerebiah, Hodijah, Sebaniah, ati Pelaniah, si wipe: Ẹ dide, ki ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin lai ati lailai: ibukun si ni fun orukọ rẹ ti o li ogo, ti o ga jù gbogbo ibukun ati iyìn lọ.


Ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori orukọ rẹ̀ nikan li o li ọlá; ogo rẹ̀ bori aiye on ọrun.


Olubukún li orukọ rẹ̀ ti o li ogo titi lai: ki gbogbo aiye ki o si kún fun ogo rẹ̀. Amin, Amin.


Ohun iyanu ti o ṣe niwaju awọn baba wọn ni ilẹ Egipti, ani ni igbẹ Soani.


Ki awọn enia ki o le mọ̀ pe iwọ, orukọ ẹni-kanṣoṣo ti ijẹ Jehofah, iwọ li Ọga-ogo lori aiye gbogbo.


Awọn enia gbọ́, nwọn warìri; ikãnu si mú awọn olugbe Palestina.


Ṣugbọn nitori eyi pãpa li emi ṣe mu ọ duro, lati fi agbara mi hàn lara rẹ; ati ki a le ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye.


Kiyesi i, iwọ o pe orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀, ati orilẹ-ède ti kò mọ̀ ọ yio sare wá sọdọ rẹ, nitori Oluwa Ọlọrun rẹ, ati nitori Ẹni-Mimọ Israeli; nitori on ti ṣe ọ li ogo.


Emi o si fi àmi kan si ãrin wọn, emi o si rán awọn ti o salà ninu wọn si awọn orilẹ-ède, si Tarṣiṣi, Puli, ati Ludi, awọn ti nfà ọrun, si Tubali, on Jafani, si awọn erekuṣu ti o jina rére, ti nwọn kò ti igbọ́ okiki mi, ti nwọn kò si ti iri ogo mi; nwọn o si rohin ogo mi lãrin awọn Keferi.


Njẹ bi iwọ ba pa gbogbo awọn enia yi bi ẹnikan, nigbana li awọn orilẹ-ède ti o ti gbọ́ okikí rẹ yio wipe,


Mose si rán onṣẹ lati Kadeṣi si ọba Edomu, wipe, Bayi ni Israeli arakunrin rẹ wi, Iwọ sá mọ̀ gbogbo ìrin ti o bá wa:


Nitori ọpọ ninu awọn ti o ni ẹmi àimọ́ ti nkigbe lohùn rara, jade wá, ati ọpọ awọn ti ẹ̀gba mbajà, ati awọn amọ́kún, a si ṣe dida ara wọn.


Yio si ṣe, bi o ba da ọ lohùn alafia, ti o si ṣilẹkun silẹ fun ọ, njẹ yio ṣe, gbogbo awọn enia ti a ba bá ninu rẹ̀, nwọn o si ma jẹ́ ọlọsin fun ọ, nwọn o si ma sìn ọ.


Bayi ni ki iwọ ki o ṣe si gbogbo ilu ti o jìna rére si ọ, ti ki iṣe ninu ilu awọn orilẹ-ède wọnyi.


Ati ohun gbogbo ti o ṣe si awọn ọba awọn Amori meji, ti mbẹ ni òke Jordani, si Sihoni ọba Heṣboni, ati si Ogu ọba Baṣani, ti mbẹ ni Aṣtarotu.


O si ṣe li opin ijọ́ mẹta, lẹhin ìgbati nwọn bá wọn dá majẹmu, ni nwọn gbọ́ pe aladugbo wọn ni nwọn, ati pe làrin wọn ni nwọn gbé wà.


Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si dé ilu wọn ni ijọ́ kẹta. Njẹ ilu wọn ni Gibeoni, ati Kefira, ati Beerotu, ati Kiriati-jearimu.


Nwọn si da Joṣua lohùn wipe, Nitoriti a sọ fun awọn iranṣẹ rẹ dajudaju, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, lati fun nyin ni gbogbo ilẹ na, ati lati pa gbogbo awọn ara ilẹ na run kuro niwaju nyin; nitorina awa bẹ̀ru nyin gidigidi nitori ẹmi wa, a si ṣe nkan yi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan