Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 9:4 - Bibeli Mimọ

4 Nwọn ṣe ẹ̀tan, nwọn si lọ nwọn si ṣe bi ẹnipe onṣẹ ni nwọn, nwọn si mú ogbologbo àpo kà ori kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ìgo-awọ ọti-waini ti lailai, ti o ya, ti a si dì;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 wọ́n lo ọgbọ́n, wọ́n tọ́jú oúnjẹ, wọ́n mú àwọn àpò ìdọ̀họ tí wọ́n ti gbó, wọ́n dì wọ́n lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Wọ́n mú awọ ìpọnmi tí ó ti gbó, tí wọ́n sì ti lẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 wọ́n dá ọgbọ́n ẹ̀tàn. Wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí aṣojú tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn kún fún ẹrù tí a fi àwọn àpò tó ti gbó dì, àti àwọn awọ ọtí wáìnì tó ti gbó tí a tún rán.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 9:4
12 Iomraidhean Croise  

Awọn ọmọ Jakobu si fi ẹ̀tan da Ṣekemu ati Hamori baba rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, nitori ti o bà Dina arabinrin wọn jẹ́:


Nitori ti emi dabi igo-awọ loju ẽfin; ṣugbọn emi kò gbagbe ilana rẹ.


Wo o, mo rán nyin lọ gẹgẹ bi agutan sãrin ikõkò; nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n bi ejò, ki ẹ si ṣe oniwà tutù bi àdaba.


Bẹ̃ni ko si ẹniti ifi waini titun sinu ogbologbo igo-awọ; bi a ba ṣe bẹ̃, igo-awọ yio bẹ́, waini a si tú jade, igo-awọ a si ṣegbe; ṣugbọn waini titun ni nwọn ifi sinu igo-awọ titun, awọn mejeji a si ṣe dede.


Ko si ẹniti ifi ọti-waini titun sinu ogbologbo ìgo; bi bẹ̃kọ ọti-waini titun a bẹ́ ìgo na, ọti-waini a si danu, ìgo na a si fàya; ṣugbọn ọti-waini titun ni ã fi sinu ìgo titun.


Oluwa rẹ̀ si yìn alaiṣõtọ iriju na, nitoriti o fi ọgbọ́n ṣe e: awọn ọmọ aiye yi sá gbọ́n ni iran wọn jù awọn ọmọ imọlẹ lọ.


Àkara wa yi ni gbigbona li a mú u fun èse wa, lati ile wa wá, li ọjọ́ ti a jade lati tọ̀ nyin wá; ṣugbọn nisisiyi, kiyesi i, o gbẹ, o si bu:


Ìgo-awọ waini wọnyi, ti awa kún, titun ni nwọn; kiyesi i, nwọn fàya: ati ẹ̀wu wa wọnyi ati bàta wa di gbigbo nitori ọ̀na ti o jìn jù.


Ṣugbọn nigbati awọn ara Gibeoni gbọ́ ohun ti Joṣua ṣe si Jeriko ati si Ai,


Ati bàta gbigbo ati lilẹ̀ li ẹsẹ̀ wọn, ati ẹ̀wu gbigbo li ara wọn; ati gbogbo àkara èse wọn o gbẹ o si hùkasi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan