Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 9:1 - Bibeli Mimọ

1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba ti mbẹ li apa ihin Jordani, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni gbogbo àgbegbe okun nla ti o kọjusi Lebanoni, awọn Hitti, ati awọn Amori, awọn Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi, gbọ́ ọ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà ní agbègbè olókè, ní òdìkejì odò Jọdani ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní etí òkun Mẹditarenia ní agbègbè Lẹbanoni, àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi, gbọ́ nípa ìṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nísinsin yìí, nígbà tí gbogbo ọba tó wà ní ìwọ̀-oòrùn Jordani gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, àwọn náà tí ó wà ní orí òkè àti àwọn tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, àti gbogbo àwọn tí ó wà ní agbègbè Òkun ńlá títí ó fi dé Lebanoni (àwọn ọba Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti Jebusi)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 9:1
32 Iomraidhean Croise  

Nwọn si wá si ilu olodi Tire, ati si gbogbo ilu awọn Hifi, ati ti awọn ara Kenaani: nwọn si jade lọ siha gusu ti Juda, ani si Beerṣeba.


Nitoriti angeli mi yio ṣaju rẹ, yio si mú ọ dé ọdọ awọn enia Amori, ati awọn Hitti, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, awọn Hifi, ati awọn Jebusi: emi a si ke wọn kuro.


Emi o si fi opinlẹ rẹ lelẹ, lati Okun Pupa wá titi yio fi dé okun awọn ara Filistia, ati lati aṣalẹ̀ nì wá dé odò nì; nitoriti emi o fi awọn olugbe ilẹ na lé nyin lọwọ; iwọ o si lé wọn jade kuro niwaju rẹ.


Emi si ti wipe, Emi o mú nyin goke jade ninu ipọnju Egipti si ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin.


Iwọ kiyesi eyiti emi palaṣẹ fun ọ li oni yi: kiyesi i, emi lé awọn Amori jade niwaju rẹ, ati awọn ara Kenaani, ati awọn ara Hitti, ati awọn ara Perissi, ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Jebusi.


Awọn ara Amaleki si ngbé ilẹ ìha gusù: ati awọn Hitti, ati awọn Jebusi, ati awọn Amori, ngbé ori-òke: awọn ara Kenaani si ngbé ẹba okun, ati ni àgbegbe Jordani.


Ati opinlẹ ìha ìwọ-õrùn, ani okun nla ni yio jẹ́ opin fun nyin: eyi ni yio jẹ́ opinlẹ ìha ìwọ-õrùn fun nyin.


Ẹ yipada, ki ẹnyin si mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si lọ si òke awọn ọmọ Amori, ati si gbogbo àgbegbe rẹ̀, ni pẹtẹlẹ̀, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni ìha gusù, ati leti okun, si ilẹ awọn ara Kenaani, ati si Lebanoni, dé odò nla nì, odò Euferate.


Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o kọja si ìha keji, ki emi si ri ilẹ rere na ti mbẹ loke Jordani, òke daradara nì, ati Lebanoni.


Ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ nì, ni ìha ẹ̀bá Jordani ni ìha ìla-õrùn, ani dé okun pẹtẹlẹ̀ nì, nisalẹ awọn orisun Pisga.


NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà a, ti o ba lé orilẹ-ède pupọ̀ kuro niwaju rẹ, awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, orilẹ-ède meje, ti o pọ̀ ti o si lagbara jù ọ lọ;


Titi OLUWA yio fi fun awọn arakunrin nyin ni isimi, gẹgẹ bi o ti fi fun nyin, ati ti awọn pẹlu yio fi gbà ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun wọn: nigbana li ẹnyin o pada si ilẹ iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla-õrùn, ẹnyin o si ní i.


Lati aginjù, ati Lebanoni yi, ani titi dé odò nla nì, odò Euferate, gbogbo ilẹ awọn Hitti, ati titi dé okun nla ni ìwọ-õrùn, eyi ni yio ṣe opin ilẹ nyin.


Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mú awọn ọba mararun nì jade lati inu ihò na tọ̀ ọ wá, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni.


Lati òke Halaki lọ, ti o lọ soke Seiri, ani dé Baali-gadi ni afonifoji Lebanoni nisalẹ òke Hermoni: ati gbogbo awọn ọba wọn li o kó, o si kọlù wọn, o si pa wọn.


Ati ilẹ awọn Gebali, ati gbogbo Lebanoni ni ìha ìla-õrùn, lati Baali-gadi nisalẹ òke Hermoni titi o fi dé atiwọ̀ Hamati:


Àla ìwọ-õrùn si dé okun nla, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni àla awọn ọmọ Juda yiká kiri gẹgẹ bi idile wọn.


Njẹ nisisiyi OLUWA Ọlọrun nyin ti fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: njẹ nisisiyi ẹ pada, ki ẹ si lọ sinu agọ́ nyin, ati si ilẹ-iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA ti fun nyin ni ìha keji Jordani.


Njẹ fun àbọ ẹ̀ya Manasse ni Mose ti fi ilẹ-iní wọn fun ni Baṣani: ṣugbọn fun àbọ ẹ̀ya ti o kù ni Joṣua fi ilẹ-iní fun pẹlu awọn arakunrin wọn ni ìha ihin Jordani ni ìwọ-õrùn. Nigbati Joṣua si rán wọn pada lọ sinu agọ́ wọn, o sure fun wọn pẹlu,


Wò o, emi ti pín awọn orilẹ-ède wọnyi ti o kù fun nyin, ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya nyin, lati Jordani lọ, pẹlu gbogbo awọn orilẹ-ède ti mo ti ke kuro, ani titi dé okun nla ni ìha ìwọ-õrùn.


Ẹnyin si gòke Jordani, ẹ si dé Jeriko: awọn ọkunrin Jeriko si fi ìja fun nyin, awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; emi si fi wọn lé nyin lọwọ.


Joṣua si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe Ọlọrun alãye mbẹ lãrin nyin, ati pe dajudaju on o lé awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Hifi, ati awọn Perissi, ati awọn Girgaṣi ati awọn Amori, ati awọn Jebusi, kuro niwaju nyin.


Awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA, si duro ṣinṣin lori ilẹ gbigbẹ lãrin Jordani, ati gbogbo awọn enia Israeli kọja lori ilẹ gbigbẹ, titi gbogbo awọn enia na fi gòke Jordani tán.


O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba Amori, ti o wà ni ìha keji Jordani ni ìwọ-õrùn, ati gbogbo awọn ọba Kenaani ti mbẹ leti okun, gbọ́ pe OLUWA ti mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa fi là a kọja, ni àiya wọn já, bẹ̃li ẹmi kò sí ninu wọn mọ́, nitori awọn ọmọ Israeli.


Bẹ̃ni OLUWA wà pẹlu Joṣua; okikí rẹ̀ si kàn ká gbogbo ilẹ na.


Awọn ọkunrin Israeli si wi fun awọn Hifi pe, Bọya ẹnyin ngbé ãrin wa; awa o ti ṣe bá nyin dá majẹmu?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan