Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 8:2 - Bibeli Mimọ

2 Iwọ o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀: kìki ikogun rẹ̀, ati ohun-ọ̀sin rẹ̀, li ẹnyin o mú ni ikogun fun ara nyin: rán enia lọ iba lẹhin ilu na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Bí o ti ṣe sí Jẹriko ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe sí Ai ati ọba rẹ̀. Ṣugbọn ẹ dá ìkógun ati àwọn ẹran ọ̀sìn tí ó wà níbẹ̀ sí, kí ẹ sì kó o gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín; ẹ ba ní ibùba lẹ́yìn odi ìlú náà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ìwọ yóò sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, ohun ìkógun wọn àti ohun ọ̀sìn wọn ni kí ẹ̀yin mú fún ara yín. Rán ènìyàn kí wọ́n ba sí ẹ̀yìn ìlú náà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 8:2
27 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Jeroboamu mu ki ogun-ẹ̀hin ki o bù wọn li ẹhin: bẹ̃ni nwọn mbẹ niwaju Juda, ati ogun-ẹhin na si mbẹ lẹhin wọn.


Nigbati nwọn bẹ̀rẹ si ikọrin ati si iyìn, Oluwa yàn ogun-ẹhin si awọn ọmọ Ammoni, Moabu ati awọn ara òke Seiri, ti o wá si Juda, a si kọlù wọn.


Nitotọ li àworan asan li enia gbogbo nrìn: nitotọ ni nwọn nyọ ara wọn lẹnu li asan: o nkó ọrọ̀ jọ, kò si mọ̀ ẹniti yio kó wọn lọ.


Enia rere fi ogún silẹ fun awọn ọmọ ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ọrọ̀ ẹlẹṣẹ̀ li a tò jọ fun olododo,


Olõtọ enia yio pọ̀ fun ibukún: ṣugbọn ẹniti o kanju ati là kì yio ṣe alaijiya.


Bi aparo ti isaba lori ẹyin ti kò yin, bẹ̃ gẹgẹ ni ẹniti o kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kì iṣe ni ododo; yio fi i silẹ lagbedemeji ọjọ rẹ̀, ati ni opin rẹ̀ yio jẹ aṣiwere.


Gbé asia soke lori odi Babeli, mu awọn iṣọ lagbara, mu awọn oluṣọ duro, ẹ yàn ẹ̀bu: nitori Oluwa gbero, o si ṣe eyi ti o wi si awọn olugbe Babeli.


Kìki ohunọ̀sin li a kó ni ikogun fun ara wa, ati ikogun ilu wọnni ti awa kó.


Ṣugbọn awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ ati ohun-ọ̀sin, ati ohun gbogbo ti mbẹ ni ilu na, ani gbogbo ikogun rẹ̀, ni ki iwọ ki o kó fun ara rẹ; ki iwọ ki o si ma jẹ ikogun awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.


OLUWA si wi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe emi ti fi on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀, le ọ lọwọ; iwọ o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni.


O SI ṣe, nigbati Adoni-sedeki ọba Jerusalemu gbọ́ pe Joṣua ti kó Ai, ti o si pa a run patapata; bi o ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀, bẹ̃li o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀; ati bi awọn ara Gibeoni ti bá Israeli ṣọrẹ, ti nwọn si ngbé ãrin wọn;


Li ọjọ́ na ni Joṣua kó Makkeda, o si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀; o pa wọn run patapata, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, kò kù ẹnikan silẹ: o si ṣe si ọba Makkeda gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko.


Ati gbogbo ikogun ilu wonyi, ati ohunọ̀sin, ni awọn ọmọ Israeli kó fun ara wọn; ṣugbọn gbogbo awọn ọkunrin ni nwọn fi oju kọlù, titi nwọn fi pa wọn run, nwọn kò kù ẹnikan silẹ ti nmí.


Nwọn si fi oju idà pa gbogbo ohun ti o wà ni ilu na run, ati ọkunrin ati obinrin, ati ewe ati àgba, ati akọ-mãlu, ati agutan, ati kẹtẹkẹtẹ.


O si mú to bi ẹgbẹdọgbọ̀n enia, o si fi wọn si ibuba li agbedemeji Betieli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn ilu na.


O si ṣe, nigbati ọba Ai ri i, nwọn yára nwọn si dide ni kùtukutu, awọn ọkunrin ilu na si jade si Israeli lati jagun, ati on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, niwaju pẹtẹlẹ̀, ibi ti a ti yàn tẹlẹ; ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn ti o ba dè e mbẹ lẹhin ilu.


Awọn ti o ba si dide kánkan kuro ni ipò wọn, bi o si ti nàwọ́ rẹ̀, nwọn sare, nwọn si wọ̀ ilu na lọ, nwọn si gbà a; nwọn si yára tinabọ ilu na.


O si ṣe, nigbati Israeli pari pipa gbogbo awọn ara ilu Ai ni igbẹ́, ati ni aginjù ni ibi ti nwọn lé wọn si, ti gbogbo wọn si ti oju idà ṣubu, titi a fi run wọn, ni gbogbo awọn ọmọ Israeli pada si Ai, nwọn si fi oju idà kọlù u.


Joṣua si dide, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun, lati gòke lọ si Ai: Joṣua si yàn ẹgba mẹdogun, alagbara akọni, o si rán wọn lo li oru.


Nigbana li ẹnyin o dide ni buba, ẹnyin o si gbà ilu na: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin yio fi i lé nyin lọwọ.


Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gbà ilu na tán, ki ẹnyin ki o si tinabọ ilu na; gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA ni ki ẹnyin ki o ṣe: wò o, mo ti fi aṣẹ fun nyin na.


Nitorina ni Joṣua ṣe rán wọn lọ: nwọn lọ iba, nwọn si joko li agbedemeji Beti-eli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn Ai: ṣugbọn Joṣua dó li oru na lãrin awọn enia.


Ṣugbọn nigbati awọn ara Gibeoni gbọ́ ohun ti Joṣua ṣe si Jeriko ati si Ai,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan