Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 7:2 - Bibeli Mimọ

2 Joṣua si rán enia lati Jeriko lọ si Ai, ti mbẹ lẹba Beti-afeni, ni ìla-õrùn Beti-eli, o si wi fun wọn pe, Ẹ gòke lọ ki ẹ si ṣamí ilẹ na. Awọn enia na gòke lọ nwọn si ṣamí Ai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Joṣua rán àwọn ọkunrin kan láti Jẹriko lọ sí ìlú Ai, lẹ́bàá Betafeni ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe amí ilẹ̀ náà wá.” Àwọn ọkunrin náà lọ ṣe amí ìlú Ai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Joṣua rán àwọn ọkùnrin láti Jeriko lọ sí Ai, tí ó súnmọ́ Beti-Afeni ní ìlà-oòrùn Beteli, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe ayọ́lẹ̀wò.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Ai wò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 7:2
18 Iomraidhean Croise  

O si ṣí kuro nibẹ̀ lọ si ori oke kan ni ìha ìla-õrùn Beteli, o si pa agọ́ rẹ̀, Beteli ni ìwọ-õrùn ati Hai ni ìla-õrùn: o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA, o si kepè orukọ OLUWA.


O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Beteli: ṣugbọn Lusi li orukọ ilu na ri.


O si gbe ọkan kalẹ ni Beteli, ati ekeji li o fi si Dani.


Ati awọn ọmọ Benjamini lati Geba de Mikmaṣi, ati Aija, ati Beteli, ati ileto wọn.


Igbimọ li a fi ifi idi ete gbogbo kalẹ: ati pẹlu èro rere ni ki o ṣigun.


Nitori nipa ìgbimọ ọgbọ́n ni iwọ o fi ṣigun rẹ: ati ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni iṣẹgun.


On de si Aiati, on ti kọja si Migroni; ni Mikmaṣi li on ko ẹrù-ogun rẹ̀ jọ si:


Hu, iwọ Heṣboni! nitori a fi Ai ṣe ijẹ: kigbe, ẹnyin ọmọbinrin Rabba! ẹ di aṣọ-ọ̀fọ mọra, ẹ pohunrere, ki ẹ si sare soke-sodo lãrin ọgba! nitori Malkomu yio jumọ lọ si igbekun, awọn alufa rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀.


Bi iwọ, Israeli, ba ṣe agbère, máṣe jẹ ki Juda ṣẹ̀; ẹ má si wá si Gilgali, bẹ̃ni ki ẹ má si goke lọ si Bet-afeni, bẹ̃ni ki ẹ má si bura pe, Oluwa mbẹ.


Wo o, mo rán nyin lọ gẹgẹ bi agutan sãrin ikõkò; nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n bi ejò, ki ẹ si ṣe oniwà tutù bi àdaba.


Nitorina ẹ kiyesi lati mã rìn ni ìwa pipé, kì iṣe bi awọn alailọgbọn, ṣugbọn bi awọn ọlọgbọn;


Ọba Jeriko, ọkan; ọba Ai, ti o wà lẹba Beti-eli, ọkan.


Àla wọn ni ìha ariwa si ti Jordani lọ; àla na si gòke lọ si ìha Jeriko ni ìha ariwa, o si là ilẹ òke lọ ni iwọ-õrùn; o si yọ si aginjù Beti-afeni.


JOṢUA ọmọ Nuni si rán ọkunrin meji jade lati Ṣittimu yọ lọ ṣe amí, wipe, Ẹ lọ iwò ilẹ na, ati Jeriko. Nwọn si lọ, nwọn si dé ile panṣaga kan, ti a npè ni Rahabu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.


Nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, nwọn si wi fun u pe, Má ṣe jẹ ki gbogbo enia ki o gòke lọ; ṣugbọn jẹ ki ìwọn ẹgba tabi ẹgbẹdogun enia ki o gòke lọ ki nwọn si kọlù Ai; má ṣe jẹ ki gbogbo enia lọ ṣiṣẹ́ nibẹ̀; nitori diẹ ni nwọn.


Awọn Filistini kó ara wọn jọ lati ba Israeli jà, ẹgbã-mẹ̃dogun kẹkẹ, ẹgbãta ọkunrin ẹlẹṣin, enia si pọ̀ bi yanrin leti okun; nwọn si goke, nwọn do ni Mikmaṣi ni iha ila õrun Bet-Afeni.


Bẹ̃li Oluwa si gbà Israeli là lọjọ na: ija na si rekọja si Bet-afeni.


O si rán a si awọn ti o wà ni Beteli ati si awọn ti o wà ni gusu Ramoti, ati si awọn ti o wà ni Jattiri.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan