Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 7:12 - Bibeli Mimọ

12 Nitorina ni awọn ọmọ Israeli kò ṣe le duro niwaju awọn ọtá wọn, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọtá wọn, nitoriti nwọn di ẹni ifibu: emi ki yio wà pẹlu nyin mọ́, bikoṣepe ẹnyin pa ohun ìyasọtọ run kuro lãrin nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn nítorí pé, wọ́n ti di ẹni ìparun. N kò ní wà pẹlu yín mọ́, àfi bí ẹ bá run àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ tí ó wà láàrin yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ìdí nì èyí tí àwọn ará Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀tá a wọn nítorí pé àwọn gan an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pa ohun ìyàsọ́tọ̀ run kúrò ní àárín yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 7:12
21 Iomraidhean Croise  

Iwọ mu wa pẹhinda fun ọta wa: ati awọn ti o korira wa nṣe ikogun fun ara wọn.


Iwọ ha kọ́, Ọlọrun, ẹniti o ṣa wa tì? ati iwọ, Ọlọrun, ti kò ba ogun wa jade lọ?


ENIA buburu sá nigbati ẹnikan kò le e: ṣugbọn olododo laiya bi kiniun.


Ṣugbọn aiṣedede nyin li o yà nyin kuro lọdọ Ọlọrun nyin, ati ẹ̀ṣẹ nyin li o pa oju rẹ̀ mọ kuro lọdọ nyin, ti on kì yio fi gbọ́.


Ati nigbati awọn enia yi, tabi woli, tabi alufa, yio bi ọ lere wipe, kini Ọ̀rọ-wuwo Oluwa? nigbana ni iwọ o wi fun wọn Ọ̀rọ-wuwo ni eyi pé: Emi o tì nyin jade, li Oluwa wi.


Gbọ́ ẹkọ́, Jerusalemu, ki ẹmi mi ki o má ba lọ kuro lọdọ rẹ; ki emi má ba sọ ọ di ahoro, ilẹ ti a kò gbe inu rẹ̀.


Bi nwọn tilẹ tọ́ ọmọ wọn dàgba, ṣugbọn emi o gbà wọn li ọwọ wọn, ti kì yio fi kù enia kan; lõtọ, egbe ni fun wọn pẹlu nigbati mo ba kuro lọdọ wọn!


Oju rẹ mọ́ jù ẹniti iwò ibi lọ, iwọ kò si lè wò ìwa-ìka: nitori kini iwọ ha ṣe nwò awọn ti nhùwa arekerekè, ti o si pa ẹnu rẹ mọ, nigbati ẹni-buburu jẹ ẹniti iṣe olododo jù u run?


Mose si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli: awọn enia na si kãnu gidigidi.


Ẹ máṣe gòke lọ, nitoriti OLUWA kò sí lãrin nyin, ki a má ba lù nyin bolẹ niwaju awọn ọtá nyin.


Nitoriti awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani mbẹ niwaju nyin, ẹnyin o si ti ipa idà ṣubu: nitoriti ẹnyin ti yipada kuro lẹhin OLUWA, nitorina OLUWA ki yio si pẹlu nyin.


Nigbana li awọn ara Amaleki sọkalẹ wá, ati awọn ara Kenaani ti ngbé ori-òke na, nwọn si kọlù wọn nwọn si ṣẹ́ wọn titi dé Horma.


Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ mú ohun irira wá sinu ile rẹ, ki iwọ ki o má ba di ẹni ifibú bi rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o korira rẹ̀ patapata, ki iwọ ki o si kà a si ohun irira patapata; nitoripe ohun ìyasọtọ ni.


Ati ẹnyin, bi o ti wù ki o ri, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu ohun ìyasọtọ, ki ẹ má ba yà a sọ̀tọ tán ki ẹ si mú ninu ohun ìyasọtọ na; ẹnyin a si sọ ibudó Israeli di ifibu, ẹnyin a si mu iyọnu bá a.


On si wipe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju õrun rẹ̀, o si wipe, Emi o jade lọ bi ìgba iṣaju, ki emi ki o si gbọ̀n ara mi. On kò si mọ̀ pe OLUWA ti kuro lọdọ on.


Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si fi wọn lé awọn akonilohun lọwọ, ti o kó wọn lẹrù, o si tà wọn si ọwọ́ awọn ọtá wọn yiká kiri, tobẹ̃ ti nwọn kò le duro mọ́ niwaju awọn ọtá wọn.


O si ṣe, nigbati angeli OLUWA sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, awọn enia na si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun.


Saulu si wipe Mu gbogbo awọn àgba enia sunmọ ihinyi, ki ẹ mọ̀, ki ẹ si ri ibiti ẹ̀ṣẹ yi wà loni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan