Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 6:3 - Bibeli Mimọ

3 Ẹnyin o si ká ilu na mọ́, gbogbo ẹnyin ologun, ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃kan. Bayi ni iwọ o ṣe ni ijọ́ mẹfa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ yóo rìn yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lojumọ fún ọjọ́ mẹfa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan pẹ̀lú gbogbo àwọn jagunjagun. Ẹ ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 6:3
9 Iomraidhean Croise  

Aworan malu si wà labẹ rẹ̀ yi i kakiri, nwọn si lọ yi agbada nla na kakiri: igbọnwọ mẹwa yi i ka, ọwọ́ meji malu li a dà ni didà wọn kan.


Ṣugbọn ẹ máṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru awọn enia ilẹ na; nitoripe onjẹ wa ni nwọn; àbo wọn ti fi wọn silẹ, OLUWA si wà pẹlu wa: ẹ máṣe bẹ̀ru wọn.


Ṣugbọn awa ni iṣura yi ninu ohun èlo amọ̀, ki ọlá nla agbara na ki o le ṣe ti Ọlọrun, ki o má ti ọdọ wa wá.


Bẹ̃li o mu ki apoti OLUWA ki o yi ilu na ká, o yi i ká lẹ̃kan: nwọn si lọ si ibudó, nwọn si wọ̀ ni ibudó.


Li ọjọ́ keji nwọn yi ilu na ká lẹ̃kan, nwọn si pada si ibudó: bẹ̃ni nwọn ṣe ni ijọ́ mẹfa.


OLUWA si wi fun Joṣua pe, Wò o, mo ti fi Jeriko lé ọ lọwọ, ati ọba rẹ̀, ati awọn alagbara akọni.


Alufa meje yio gbé ipè jubeli meje niwaju apoti na: ni ijọ́ keje ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃meje, awọn alufa yio si fọn ipè wọnni.


O si wi fun awọn enia pe, Ẹ kọja, ki ẹ si yi ilu na ká, ki awọn ti o hamọra ki o si kọja niwaju apoti OLUWA.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan