Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 6:2 - Bibeli Mimọ

2 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Wò o, mo ti fi Jeriko lé ọ lọwọ, ati ọba rẹ̀, ati awọn alagbara akọni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti fi Jẹriko lé ọ lọ́wọ́ ati ọba wọn ati àwọn akikanju wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nígbà náà ni Olúwa wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo ti fi Jeriko lé ọ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọba rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 6:2
20 Iomraidhean Croise  

Dafidi si bere lọdọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke tọ̀ awọn Filistini bi? iwọ o fi wọn le mi lọwọ bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe, Goke lọ: nitoripe, dajudaju emi o fi awọn Filistini le ọ lọwọ.


Bẹ̃li awọn ọmọ na wọ inu rẹ̀ lọ, nwọn si gbà ilẹ na, iwọ si tẹ ori awọn ara ilẹ na ba niwaju wọn, awọn ara Kenaani, o si fi wọn le ọwọ wọn, pẹlu ọba wọn, ati awọn enia ilẹ na, ki nwọn ki o le fi wọn ṣe bi o ti wù wọn.


O si nyi ìgba ati akokò pada: o nmu ọba kuro, o si ngbe ọba leke: o si nfi ọgbọ́n fun awọn ọlọgbọ́n, ati ìmọ fun awọn ti o mọ̀ oye:


Li ọjọ awọn ọba wọnyi li Ọlọrun ọrun yio gbe ijọba kan kalẹ, eyi ti a kì yio le parun titi lai: a kì yio si fi ijọba na le orilẹ-ède miran lọwọ, yio si fọ tutu, yio si pa gbogbo ijọba wọnyi run, ṣugbọn on o duro titi lailai.


Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀.


Gbogbo awọn araiye li a si kà si bi ohun asan, on a si ma ṣe gẹgẹ bi o ti wù u ninu ogun ọrun, ati larin awọn araiye: kò si si ẹniti idá ọwọ rẹ̀ duro, tabi ẹniti iwi fun u pe, Kini iwọ nṣe nì?


Iwọ ọba! Ọlọrun Ọga-ogo fi ijọba, ati ọlanla, ati ogo, ati ọlá fun Nebukadnessari, baba rẹ:


On o si fi awọn ọba wọn lé ọ lọwọ, iwọ o si pa orukọ wọn run kuro labẹ ọrun: kò sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ, titi iwọ o fi run wọn tán.


Ọba Jeriko, ọkan; ọba Ai, ti o wà lẹba Beti-eli, ọkan.


Nwọn si wi fun Joṣua pe, Nitõtọ li OLUWA ti fi gbogbo ilẹ na lé wa lọwọ; nitoripe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori wa.


O si wi fun awọn ọkunrin na pe, Emi mọ̀ pe OLUWA ti fun nyin ni ilẹ yi, ati pe ẹ̀ru nyin bà ni, ati pe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori nyin.


OLUWA si sọ fun Joṣua pe,


(NJẸ a há Jeriko mọ́ gága nitori awọn ọmọ Israeli: ẹnikẹni kò jade, ẹnikẹni kò si wọle.)


Ẹnyin o si ká ilu na mọ́, gbogbo ẹnyin ologun, ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃kan. Bayi ni iwọ o ṣe ni ijọ́ mẹfa.


OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o má ṣe fò ọ: mú gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ ki iwọ ki o si dide, ki o si gòke lọ si Ai: kiyesi i, emi ti fi ọba Ai, ati awọn enia rẹ̀, ati ilunla rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀ lé ọ lọwọ:


OLUWA, Ọlọrun Israeli, si fi Sihoni, ati gbogbo enia rẹ̀ lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn: Israeli si gbà gbogbo ilẹ awọn Amori, awọn enia ilẹ na.


Iwọ ki yio ha gbà eyiti Kemoṣu oriṣa rẹ fi fun ọ lati ní? Bẹ̃li ẹnikẹni ti OLUWA Ọlọrun wa ba lé kuro niwaju wa, ilẹ wọn ni awa o gbà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan