Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 5:2 - Bibeli Mimọ

2 Nigbana li OLUWA wi fun Joṣua pe, Fi okuta ṣe abẹ ki iwọ ki o si tun kọ awọn ọmọ Israeli nilà lẹ̃keji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Nígbà náà ni OLUWA wí fún Joṣua pé, “Fi akọ òkúta ṣe abẹ, kí o sì fi kọ ilà abẹ́ lẹẹkeji fún àwọn ọmọ Israẹli.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nígbà náà ni Olúwa wí fún Joṣua pé, “Fi akọ òkúta ṣe abẹ kí o sì kọ àwọn ọmọ Israẹli ní ilà ní ìgbà ẹ̀ẹ̀kejì.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 5:2
8 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni Sippora mú okuta mimú, o si kọ ọmọ rẹ̀ ni ilà abẹ, o si sọ ọ si ẹsẹ̀ Mose, o si wipe, Ọkọ ẹlẹjẹ ni iwọ fun mi nitõtọ.


Ṣugbọn Ju ti inu ni Ju, ati ikọla ti ọkàn, ninu ẹmi ni, kì iṣe ti ode ara; iyìn ẹniti kò si lọdọ enia, bikoṣe lọdọ Ọlọrun.


O si gbà àmi ikọla, èdidi ododo igbagbọ́ ti o ni nigbati o wà li aikọla: ki o le ṣe baba gbogbo awọn ti o gbagbọ́, bi a kò tilẹ kọ wọn ni ilà; ki a le kà ododo si wọn pẹlu:


Nitorina ẹ kọ àiya nyin nilà, ki ẹ má si ṣe ọlọrùn lile mọ́.


OLUWA Ọlọrun rẹ yio si kọ àiya rẹ nilà, ati àiya irú-ọmọ rẹ, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo, ki iwọ ki o le yè.


Ninu ẹniti a ti fi ikọla ti a kò fi ọwọ kọ kọ nyin ni ila, ni bibọ ara ẹ̀ṣẹ silẹ, ninu ikọla Kristi:


Joṣua si ṣe abẹ okuta, o si kọ awọn ọmọ Israeli nilà, ni Gibeati-haaralotu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan