Joṣua 5:1 - Bibeli Mimọ1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba Amori, ti o wà ni ìha keji Jordani ni ìwọ-õrùn, ati gbogbo awọn ọba Kenaani ti mbẹ leti okun, gbọ́ pe OLUWA ti mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa fi là a kọja, ni àiya wọn já, bẹ̃li ẹmi kò sí ninu wọn mọ́, nitori awọn ọmọ Israeli. Faic an caibideilYoruba Bible1 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Amori, tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, ati gbogbo ọba àwọn ará ilẹ̀ Kenaani, tí wọ́n wà ní etí Òkun gbọ́ pé OLUWA mú kí odò Jọdani gbẹ nítorí àwọn ọmọ Israẹli, títí tí wọ́n fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, àyà wọn já, ìdààmú sì bá wọn, nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba Amori ti ìlà-oòrùn Jordani àti gbogbo àwọn ọba Kenaani tí ń bẹ létí Òkun gbọ́ bí Olúwa ti mú Jordani gbẹ ní iwájú àwọn ọmọ Israẹli títí ti a fi kọjá, ọkàn wọn pami, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ìgboyà mọ́ láti dojúkọ àwọn ọmọ Israẹli. Faic an caibideil |
NIGBATI a si ti ṣe nkan wọnyi tan, awọn ijoye wá si ọdọ mi, wipe, Awọn enia Israeli, ati awọn alufa, pẹlu awọn ọmọ Lefi kò ya ara wọn si ọ̀tọ kuro ninu awọn enia ilẹ wọnni, gẹgẹ bi irira wọn, ti awọn ara Kenaani, awọn ara Hitti, awọn ara Perisi, awọn ara Jebusi, awọn ara Ammoni, awọn ara Moabu, awọn ara Egipti, ati ti awọn ara Amori.