Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 4:3 - Bibeli Mimọ

3 Ki ẹnyin si paṣẹ fun wọn pe. Ẹ gbé okuta mejila lati ihin lọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa gbé duro ṣinṣin nì, ki ẹnyin ki o si rù wọn kọja pẹlu nyin, ẹ si fi wọn si ibùsun, ni ibi ti ẹnyin o sùn li alẹ yi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Kí o pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n gbé òkúta mejila láàrin odò Jọdani yìí, lọ́gangan ibi tí àwọn alufaa dúró sí, kí wọ́n gbé wọn lọ́wọ́ bí ẹ ti ń lọ, kí ẹ sì kó wọn jọ sí ibi tí ẹ óo sùn lálẹ́ òní.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 kí o sì pàṣẹ fún wọn pé Ẹ gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani ní ibi tí àwọn àlùfáà dúró sí, kí ẹ sì rù wọn kọjá, kí ẹ sì gbé wọn sí ibi tí ẹ̀yin yóò sùn ní alẹ́ yìí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 4:3
11 Iomraidhean Croise  

Okuta yi, ti mo fi lelẹ ṣe ọwọ̀n ni yio si ṣe ile Ọlọrun: ati ninu ohun gbogbo ti iwọ o fi fun mi, emi o si fi idamẹwa rẹ̀ fun ọ.


Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, má si ṣe gbagbe gbogbo ore rẹ̀:


Oluwa mbẹ ninu tempili mimọ́ rẹ̀, itẹ́ Oluwa mbẹ li ọrun: oju rẹ̀ nwò, ipenpeju rẹ̀ ndán awọn ọmọ enia wò.


O si da wọn lohùn, o wi fun wọn pe, Mo wi fun nyin, Bi awọn wọnyi ba pa ẹnu wọn mọ́, awọn okuta yio kigbe soke.


Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Ẹ kiyesi i, okuta yi ni ẹlẹri fun wa; nitori o ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o bá wa sọ: nitorina yio ṣe ẹlẹri si nyin, ki ẹnyin má ba sẹ́ Ọlọrun nyin.


Yio si ṣe, lojukanna bi atẹlẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti OLUWA, Oluwa gbogbo aiye, ba ti tẹ̀ omi Jordani, omi Jordani yio ke kuro, ani omi ti nti òke ṣànwá; yio si duro bi òkiti kan.


Nigbana ni Joṣua pè awọn ọkunrin mejila, ti o ti pèse silẹ ninu awọn ọmọ Israeli, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya:


Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi Joṣua ti paṣẹ, nwọn si gbé okuta mejila lati inu ãrin Jordani lọ, bi OLUWA ti wi fun Joṣua, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli; nwọn si rù wọn kọja pẹlu wọn lọ si ibùsun, nwọn si gbé wọn kalẹ nibẹ̀.


Samueli si mu okuta kan, o si gbe e kalẹ lagbedemeji Mispe ati Seni, o si pe orukọ rẹ̀ ni Ebeneseri, wipe: Titi de ihin li Oluwa ràn wa lọwọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan