Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 4:10 - Bibeli Mimọ

10 Nitoriti awọn alufa ti o rù apoti na duro lãrin Jordani, titi ohun gbogbo fi pari ti OLUWA palaṣẹ fun Joṣua lati sọ fun awọn enia, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Mose palaṣẹ fun Joṣua: awọn enia na si yára nwọn si rekọja.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Nítorí pé àwọn alufaa tí ó gbé Àpótí Majẹmu OLUWA dúró láàrin odò Jọdani, títí tí àwọn eniyan náà fi ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé kí Joṣua sọ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárín Jordani títí gbogbo nǹkan tí Olúwa pàṣẹ fún Joṣua fi di ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún Joṣua. Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 4:10
14 Iomraidhean Croise  

Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́.


Nwọn si yan àkara iyẹfun pipò alaiwu ti nwọn mú jade ti Egipti wá, nwọn kò sa fi iwukàra si i; nitoriti a tì wọn jade kuro ni Egipti, nwọn kò si le duro, bẹ̃ni nwọn kò pèse ohun jijẹ kan fun ara wọn.


MÁṢE leri ara rẹ niti ọjọ ọla, nitoriti iwọ kò mọ̀ ohun ti ọjọ kan yio hù jade.


Ohunkohun ti ọwọ rẹ ri ni ṣiṣe, fi agbara rẹ ṣe e; nitoriti kò si ete, bẹ̃ni kò si ìmọ, tabi ọgbọ́n, ni isa-okú nibiti iwọ nrè.


Nitorina bayi li Oluwa Jehofah wi, pe, Kiyesi i, emi gbe okuta kan kalẹ ni Sioni fun ipilẹ, okuta ti a dán wò, okuta igun-ile iyebiye, ipilẹ ti o daju: ẹniti o gbagbọ kì yio sá.


(Nitori o wipe, emi ti gbohùn rẹ li akokò itẹwọgbà, ati li ọjọ igbala ni mo si ti ràn ọ lọwọ: kiyesi i, nisisiyi ni akokò itẹwọgbà; kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala.)


Mose si kọwe ofin yi, o si fi i fun awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti ima rù apoti majẹmu OLUWA, ati fun gbogbo awọn àgba Israeli.


Ẹnyin si gòke Jordani, ẹ si dé Jeriko: awọn ọkunrin Jeriko si fi ìja fun nyin, awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; emi si fi wọn lé nyin lọwọ.


Yio si ṣe, lojukanna bi atẹlẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti OLUWA, Oluwa gbogbo aiye, ba ti tẹ̀ omi Jordani, omi Jordani yio ke kuro, ani omi ti nti òke ṣànwá; yio si duro bi òkiti kan.


O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia na rekọja tán, ni apoti OLUWA rekọja, ati awọn alufa, li oju awọn enia.


Joṣua si tò okuta mejila jọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na gbé duro: nwọn si mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan