Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 3:7 - Bibeli Mimọ

7 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi gbé ọ ga li oju gbogbo Israeli, ki nwọn ki o le mọ̀ pe, gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o wà pẹlu rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Lónìí ni n óo bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọ ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè mọ̀ pé bí mo ti wà pẹlu Mose, bẹ́ẹ̀ ni n óo wà pẹlu rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Israẹli, kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 3:7
13 Iomraidhean Croise  

Oluwa si gbé Solomoni ga gidigidi li oju gbogbo Israeli, o si fi ọlá nla ọba fun u bi iru eyi ti kò wà fun ọba kan ṣaju rẹ̀ lori Israeli.


A si mu Solomoni, ọmọ Dafidi, lagbara lori ijọba rẹ̀, Oluwa Ọlọrun rẹ̀ si wà pẹlu rẹ̀, o si gbé e ga gidigidi.


Kili enia ti iwọ o ma kokìki rẹ̀? ati ti iwọ iba fi gbe ọkàn rẹ le e?


Iwọ ti fi asà igbala rẹ fun mi pẹlu: ọwọ ọ̀tun rẹ si gbé mi duro, ati ìwa-pẹlẹ rẹ sọ mi di nla.


NKAN wọnyi ni Jesu sọ, o si gbé oju rẹ̀ soke ọrun, o si wipe, Baba, wakati na de: yìn Ọmọ rẹ logo, ki Ọmọ rẹ ki o le yìn ọ logo pẹlu:


Gẹgẹ bi ìnàgà ati ireti mi pe ki oju ki o máṣe tì mi li ohunkohun, ṣugbọn pẹlu igboiya gbogbo, bi nigbagbogbo, bẹ̃ nisisiyi pẹlu a o gbé Kristi ga lara mi, ibã ṣe nipa ìye, tabi nipa ikú.


Gẹgẹ bi awa ti gbọ́ ti Mose li ohun gbogbo, bẹ̃li awa o gbọ́ tirẹ: kìki ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o wà pẹlu rẹ, gẹgẹ bi o ti wà pẹlu Mose.


Ki yio sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo: gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o si wà pẹlu rẹ: Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃li emi ki yio kọ̀ ọ.


Emi kò ha paṣẹ fun ọ bi? Ṣe giri ki o si mu àiya le; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ ba nlọ.


Joṣua si wi fun awọn alufa pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki ẹ si kọja siwaju awọn enia. Nwọn si gbé apoti majẹmu na, nwọn si ṣaju awọn enia.


Iwọ o si paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na pe, Nigbati ẹnyin ba dé eti odò Jordani, ki ẹnyin ki o duro jẹ ni Jordani.


Li ọjọ́ na OLUWA gbé Joṣua ga li oju gbogbo Israeli: nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, gẹgẹ bi nwọn ti bẹ̀ru Mose li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan