Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 3:6 - Bibeli Mimọ

6 Joṣua si wi fun awọn alufa pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki ẹ si kọja siwaju awọn enia. Nwọn si gbé apoti majẹmu na, nwọn si ṣaju awọn enia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Joṣua bá sọ fún àwọn alufaa pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu náà kí ẹ sì máa lọ níwájú àwọn eniyan yìí.” Wọ́n bá gbé Àpótí Majẹmu náà, wọ́n sì ń lọ níwájú wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Joṣua sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ̀yin, ẹ gbé àpótí ẹ̀rí náà kí ẹ̀yin kí ó sì máa lọ ṣáájú àwọn ènìyàn.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e sókè, wọ́n sì ń lọ ní iwájú u wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 3:6
11 Iomraidhean Croise  

Gbogbo awọn agbàgba Israeli si wá, awọn alufa si gbe apoti-ẹri.


Gbogbo awọn àgbagba Israeli si wá; awọn ọmọ Lefi si gbé apoti-ẹri na.


Ẹniti nfọ́ni ti dide niwaju wọn: nwọn ti fọ́, nwọn kọja lãrin bode, nwọn si ti jade lọ nipa rẹ̀: ọba wọn o si kọja lọ niwaju wọn, Oluwa ni yio si ṣe olori wọn.


Nwọn si ṣí kuro ni òke OLUWA ni ìrin ijọ́ mẹta: apoti majẹmu OLUWA si ṣiwaju wọn ni ìrin ijọ́ mẹta, lati wá ibi isimi fun wọn.


Njẹ bi iwọ ba pa gbogbo awọn enia yi bi ẹnikan, nigbana li awọn orilẹ-ède ti o ti gbọ́ okikí rẹ yio wipe,


Nibiti aṣaju wa ti wọ̀ lọ fun wa, ani Jesu, ti a fi jẹ Olori Alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.


Nwọn si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Nigbati ẹnyin ba ri apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti ẹ ba si ri awọn alufa awọn ọmọ Lefi rù u, nigbana li ẹnyin o ṣí kuro ni ipò nyin, ẹnyin o si ma tọ̀ ọ lẹhin.


Joṣua si wi fun awọn enia pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́: nitori li ọla OLUWA yio ṣe ohuniyanu lãrin nyin.


OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi gbé ọ ga li oju gbogbo Israeli, ki nwọn ki o le mọ̀ pe, gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o wà pẹlu rẹ.


Joṣua ọmọ Nuni si pè awọn alufa, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki alufa meje ki o gbé ipè jubeli meje nì niwaju apoti OLUWA.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan