Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 3:10 - Bibeli Mimọ

10 Joṣua si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe Ọlọrun alãye mbẹ lãrin nyin, ati pe dajudaju on o lé awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Hifi, ati awọn Perissi, ati awọn Girgaṣi ati awọn Amori, ati awọn Jebusi, kuro niwaju nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Èyí ni ẹ óo fi mọ̀ pé Ọlọrun alààyè wà láàrin yín, kò sì ní kùnà láti lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi, àwọn ará Perisi, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Jebusi, jáde fun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè wà ní àárín yín àti pé dájúdájú yóò lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, Hifi, Peresi, Girgaṣi, Amori àti Jebusi jáde níwájú u yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 3:10
37 Iomraidhean Croise  

Ati awọn enia Amori, ati awọn enia Kenaani, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Jebusi.


Mikaiah si wipe, Ni pipada bi iwọ ba pada bọ̀ li alafia, njẹ Oluwa kò ti ipa mi sọ̀rọ. O si wipe, Ẹ gbọ́, ẹnyin enia gbogbo!


Bọya Oluwa Ọlọrun rẹ yio gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Rabṣake ẹniti ọba Assiria oluwa rẹ̀ ti rán lati kẹgàn Ọlọrun alãyè, yio si ba a wi nitori ọ̀rọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ ti gbọ́: njẹ nitorina, gbé adura rẹ soke fun awọn iyokù ti o kù.


Ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Amori, ati awọn ara Girgaṣi,


Ongbẹ Ọlọrun ngbẹ ọkàn mi, ti Ọlọrun alãye: nigbawo li emi o wá, ti emi o si yọju niwaju Ọlọrun.


A mọ̀ Oluwa, nipa idajọ ti o nṣe: nipa iṣẹ ọwọ enia buburu li a fi ndẹkùn mu u.


O si sọ orukọ ibẹ̀ ni Massa, ati Meriba, nitori asọ̀ awọn ọmọ Israeli, ati nitoriti nwọn dan OLUWA wò pe, OLUWA ha mbẹ lãrin wa, tabi kò si?


Emi si sọkalẹ wa lati gbà wọn lọwọ awọn ara Egipti, ati lati mú wọn goke ti ilẹ na wá si ilẹ rere ati nla, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin; si ibi ti awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi.


Emi o si rán angeli kan si iwaju rẹ; emi o si lé awọn ara Kenaani, awọn ara Amori, ati awọn ara Hitti, ati awọn ara Perissi, ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Jebusi jade:


Nitorina, Oluwa tikalarẹ̀ yio fun nyin li àmi kan, kiyesi i, Wundia kan yio loyun, yio si bi ọmọkunrin kan, yio si pe orukọ rẹ̀ ni Immanueli.


Ṣugbọn Oluwa, Ọlọrun otitọ ni, on ni Ọlọrun alãye, ati Ọba aiyeraiye! aiye yio warìri nigbati o ba binu, orilẹ-ède kì yio le duro ni ibinu rẹ̀.


Ṣugbọn iye awọn ọmọ Israeli yio ri bi iyanrìn okun, ti a kò le wọ̀n ti a kò si lè ikà; yio si ṣe, ni ibi ti a gbe ti wi fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, ibẹ̀ li a o gbe wi fun wọn pe, Ẹnyin li ọmọ Ọlọrun alãyè.


Awọn ara Amaleki si ngbé ilẹ ìha gusù: ati awọn Hitti, ati awọn Jebusi, ati awọn Amori, ngbé ori-òke: awọn ara Kenaani si ngbé ẹba okun, ati ni àgbegbe Jordani.


Simoni Peteru dahùn, wipe, Kristi, Ọmọ Ọlọrun alãye ni iwọ iṣe.


Awa si ti gbagbọ́, a si mọ̀ pe, iwọ ni Kristi na, Ọmọ Ọlọrun alãye.


Nigbana ni ibinu mi yio rú si wọn li ọjọ́ na, emi o si kọ̀ wọn silẹ, emi o si pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, a o si jẹ wọn run, ati ibi pupọ̀ ati iyọnu ni yio bá wọn; tobẹ̃ ti nwọn o si wi li ọjọ́ na pe, Kò ha jẹ́ pe nitoriti Ọlọrun wa kò sí lãrin wa ni ibi wọnyi ṣe bá wa?


Nitoripe tani mbẹ ninu gbogbo araiye ti o ti igbọ́ ohùn Ọlọrun alãye ti nsọ̀rọ lati ãrin iná wá, bi awa ti gbọ́, ti o si wà lãye?


NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà a, ti o ba lé orilẹ-ède pupọ̀ kuro niwaju rẹ, awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, orilẹ-ède meje, ti o pọ̀ ti o si lagbara jù ọ lọ;


Ki iwọ ki o máṣe fòya wọn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lãrin rẹ, Ọlọrun ti o tobi ti o si lẹrù.


Nitoripe awọn tikarawọn ròhin nipa wa, irú iwọle ti awa ti ni sọdọ nyin, bi ẹnyin si ti yipada si Ọlọrun kuro ninu ère lati mã sìn Ọlọrun alãye ati otitọ;


Ohun ẹ̀ru ni lati ṣubu si ọwọ́ Ọlọrun alãye.


Ati si awọn ara Kenaani ni ìha ìla-õrùn ati ni ìha ìwọ-õrùn, ati awọn Amori, ati si awọn Hitti, ati si awọn Perissi, ati si awọn Jebusi lori òke, ati si awọn Hifi nisalẹ Hermoni ni ilẹ Mispa.


Ni ilẹ òke, ati ni ilẹ titẹju, ati ni pẹtẹlẹ̀, ati li ẹsẹ̀-òke, ati li aginjù, ati ni Gusù; awọn Hitti, awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi:


Ohunkohun kò tase ninu ohun rere ti OLUWA ti sọ fun ile Israeli; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ.


Finehasi ọmọ Eleasari alufa si wi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Manasse pe, Li oni li awa mọ̀ pe OLUWA wà lãrin wa, nitoriti ẹnyin kò dẹ̀ṣẹ yi si OLUWA: nisisiyi ẹnyin yọ awọn ọmọ Israeli kuro lọwọ OLUWA.


Ẹnyin si gòke Jordani, ẹ si dé Jeriko: awọn ọkunrin Jeriko si fi ìja fun nyin, awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; emi si fi wọn lé nyin lọwọ.


Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ ihin, ki ẹ si gbọ́ ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun nyin.


O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba ti mbẹ li apa ihin Jordani, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni gbogbo àgbegbe okun nla ti o kọjusi Lebanoni, awọn Hitti, ati awọn Amori, awọn Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi, gbọ́ ọ;


Dafidi si wi fun awọn ọkunrin ti o duro li ọdọ rẹ̀ pe, Kili a o ṣe fun ọkunrin na ti o ba pa Filistini yi, ti o si mu ẹgàn na kuro li ara Israeli? tali alaikọla Filistini yi iṣe, ti yio fi ma gan ogun Ọlọrun alãye?


Dafidi si dahun, o si wi fun Ahimeleki ọkan ninu awọn ọmọ Heti, ati fun Abiṣai ọmọ Seruia arákùnrin Joabu, pe, Tani o ba mi sọkalẹ lọ sọdọ Saulu ni ibudo? Abiṣai si wipe, emi o ba ọ sọkalẹ lọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan