Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 24:6 - Bibeli Mimọ

6 Emi si mú awọn baba nyin jade kuro ni Egipti: ẹnyin si dé okun; awọn ara Egipti si lepa awọn baba nyin ti awọn ti kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin dé Okun Pupa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Mo kó àwọn baba yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí ẹ dé etí òkun, àwọn ará Ijipti kó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì lé àwọn baba yín títí dé etí Òkun Pupa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Ejibiti, ẹ wá sí Òkun, àwọn ará Ejibiti lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun Pupa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 24:6
11 Iomraidhean Croise  

Iwọ si ti pin okun niwaju wọn, nwọn si la arin okun ja li ori ilẹ gbigbẹ; iwọ sọ awọn oninunibini wọn sinu ibú, bi okuta sinu omi lile.


O pin okun ni ìya, o si mu wọn là a ja; o si mu omi duro bi bèbe.


Awọn ọmọ Israeli si rìn lati Ramesesi lọ si Sukkotu, nwọn to ìwọn ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀ ọkunrin, li àika ọmọde.


O si ṣe li ọjọ́ na gan, OLUWA mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn.


Nitori mo ti mu ọ goke lati ilẹ Egipti wá, mo si rà ọ padà lati ile ẹrú wá; mo si rán Mose, Aaroni, ati Miriamu siwaju rẹ.


On li o mu wọn jade, lẹhin igbati o ṣe iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi ni ilẹ Egipti, ati li Okun pupa, ati li aginjù li ogoji ọdún.


Nipa igbagbọ́ ni nwọn là okun pupa kọja bi ẹnipe ni iyangbẹ ilẹ: ti awọn ara Egipti danwò, ti nwọn si rì.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan