Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 24:5 - Bibeli Mimọ

5 Mo si rán Mose ati Aaroni, mo si yọ Egipti lẹnu, gẹgẹ bi eyiti mo ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin na mo si mú nyin jade.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Mo rán Mose ati Aaroni sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá àwọn ará Ijipti jà, lẹ́yìn náà mo ko yín jáde.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 “ ‘Nígbà náà ni mo rán Mose àti Aaroni, mo sì yọ Ejibiti lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 24:5
13 Iomraidhean Croise  

O si fi ayọ̀ mu awọn enia rẹ̀ jade, ati awọn ayanfẹ rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀:


Fun ẹniti o kọlù Egipti lara awọn akọbi wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.


Awọn ọmọ Israeli si rìn lati Ramesesi lọ si Sukkotu, nwọn to ìwọn ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀ ọkunrin, li àika ọmọde.


O si ṣe li opin irinwo ọdún o le ọgbọ̀n, ani li ọjọ́ na gan, li o si ṣe ti gbogbo ogun OLUWA jade kuro ni ilẹ Egipti.


O si ṣe li ọjọ́ na gan, OLUWA mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn.


Nitorina wá nisisiyi, emi o si rán ọ si Farao, ki iwọ ki o le mú awọn enia mi, awọn ọmọ Israeli, lati Egipti jade wá.


Awọn wọnyi li o bá Farao ọba Egipti sọ̀rọ lati mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni Egipti: wọnyi ni Mose ati Aaroni na.


Emi si mú awọn baba nyin jade kuro ni Egipti: ẹnyin si dé okun; awọn ara Egipti si lepa awọn baba nyin ti awọn ti kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin dé Okun Pupa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan