Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 24:1 - Bibeli Mimọ

1 JOṢUA si pè gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli jọ si Ṣekemu, o si pè awọn àgba Israeli, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn; nwọn si fara wọn hàn niwaju Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Joṣua pe gbogbo ẹ̀yà Israẹli jọ sí Ṣekemu, ó pe gbogbo àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso ilẹ̀ Israẹli; gbogbo wọn sì kó ara wọn jọ níwájú OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà náà ni Joṣua pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli jọ ní Ṣekemu. Ó pe àwọn àgbàgbà, àwọn olórí, onídàájọ́ àti àwọn ìjòyè Israẹli, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 24:1
13 Iomraidhean Croise  

Abramu si là ilẹ na kọja lọ si ibi ti a npè ni Ṣekemu, si igbo More. Awọn ara Kenaani si wà ni ilẹ na ni ìgba na.


Nwọn si fi gbogbo àjeji oriṣa ti o wà lọwọ wọn fun Jakobu, ati gbogbo oruka eti ti o wà li eti wọn: Jakobu si pa wọn mọ́ li abẹ igi oaku ti o wà leti Ṣekemu.


REHOBOAMU si lọ si Ṣekemu, nitori gbogbo Israeli li o wá si Ṣekemu lati fi i jẹ ọba.


ỌBA si ranṣẹ, nwọn si pè gbogbo awọn àgba Juda ati Jerusalemu jọ sọdọ rẹ̀.


Nitorina ni mo si ti ranṣẹ si ọ lojukanna, iwọ si ṣeun ti o fi wá. Gbogbo wa pé niwaju Ọlọrun nisisiyi, lati gbọ́ ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun ọ lati ọdọ Ọlọrun wá.


Nitorina, ẹ pa ọ̀rọ majẹmu yi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn, ki ẹnyin ki o le ma ri ire ninu ohun gbogbo ti ẹnyin nṣe.


Nwọn si yàn Kedeṣi ni Galili ni ilẹ òke Naftali, ati Ṣekemu ni ilẹ òke Efraimu, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni) ni ilẹ òke Juda.


Joṣua si pè gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn, o si wi fun wọn pe, Emi di arugbó tán, emi si pọ̀ li ọjọ́:


Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ Israeli, ati gbogbo awọn enia na gòke lọ, nwọn wá si Beti-eli, nwọn sọkun, nwọn si joko nibẹ̀ niwaju OLUWA, nwọn si gbàwẹ li ọjọ́ na titi di aṣalẹ; nwọn si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia niwaju OLUWA.


Ẹnyin si kọ̀ Ọlọrun nyin loni, ẹniti on tikara rẹ́ ti gbà nyin kuro lọwọ́ gbogbo awọn ọta nyin, ati gbogbo wahala nyin; ẹnyin si ti wi fun u pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn awa nfẹ ki o fi ẹnikan jọba lori wa. Nisisiyi ẹ duro niwaju Oluwa nipa ẹyà nyin, ati nipa ẹgbẹgbẹrun nyin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan