Joṣua 23:2 - Bibeli Mimọ2 Joṣua si pè gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn, o si wi fun wọn pe, Emi di arugbó tán, emi si pọ̀ li ọjọ́: Faic an caibideilYoruba Bible2 ó bá pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, àwọn àgbààgbà, ati àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso, ó wí fún wọn pé, “Mo ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí mi; Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní2 Ó sì pe gbogbo Israẹli jọ: àgbàgbà wọn, olórí wọn, adájọ́ àti àwọn ìjòyè, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti pọ̀ ní ọdún èmi ti di arúgbó. Faic an caibideil |
DAFIDI si kó gbogbo ijoye Israeli jọ, awọn ijoye ẹ̀ya, ati awọn ijoye awọn ẹgbẹ ti nṣe iranṣẹ fun ọba, ati awọn ijoye lori ẹgbẹgbẹrun, ati awọn ijoye lori ọrọrun, ati awọn ijoye lori gbogbo ọrọ̀ ati ini ọba, ati ti awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu awọn balogun, ati pẹlu awọn alagbara enia, ati gbogbo akọni enia si Jerusalemu.