Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 23:1 - Bibeli Mimọ

1 O si ṣe li ọjọ́ pipọ̀ lẹhin ti OLUWA ti fi isimi fun Israeli lọwọ gbogbo awọn ọtá wọn yiká, ti Joṣua di arugbó, ti o si pọ̀ li ọjọ́;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ó pẹ́ lẹ́yìn tí OLUWA ti fún Israẹli ní ìsinmi, tí kò sí ogun mọ́ láàrin àwọn ati gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó yí wọn ká, Joṣua ti di àgbàlagbà ní àkókò yìí, ogbó sì ti dé sí i;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, nígbà tí Olúwa sì ti fún Israẹli ní ìsinmi kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká, nígbà náà Joṣua sì ti di arúgbó.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 23:1
15 Iomraidhean Croise  

Abrahamu si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú li ogbologbo, arugbo, o kún fun ọjọ́; a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀.


DAFIDI ọba si di arugbo, ọjọ rẹ̀ si pọ̀; nwọn si fi aṣọ bò o lara, ṣugbọn kò mõru.


Nitori Dafidi wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli ti fi isimi fun awọn enia rẹ̀, on si ngbé Jerusalemu lailai:


NJẸ awọn ọmọ Israeli nipa iye wọn, eyini ni, awọn olori baba, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn ijoye wọn ti nsìn ọba ni olukuluku ọ̀na li ẹgbẹgbẹ, ti nwọle ti si njade li oṣoṣù ni gbogbo oṣù ọdun, jẹ́ ẹgbã mejila.


Bẹ̃ni Abijah sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu Dafidi: Asa ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. Li ọjọ rẹ̀, ilẹ na wà li alafia li ọdun mẹwa.


O si mu ibi giga wọnni ati ọwọ̀n-õrun wọnni kuro lati inu gbogbo ilu Juda: ijọba na si wà li alafia niwaju rẹ̀.


Bẹ̃ni ijọba Jehoṣafati wà li alafia: nitoriti Ọlọrun rẹ̀ fun u ni isimi yikakiri.


O mu ọ̀tẹ tan de opin aiye; o ṣẹ́ ọrun, o si ke ọ̀kọ meji; o si fi kẹkẹ́ ogun jona.


Gẹgẹ bi ẹran ti isọ̀kalẹ lọ si afonifoji, bẹ̃ni Ẹmi Oluwa mu u simi: bẹ̃ni iwọ tọ́ awọn enia rẹ, lati ṣe orukọ ti o li ogo fun ara rẹ.


O si wi fun wọn pe, Emi di ẹni ọgọfa ọdún li oni; emi kò le ma jade ki nsi ma wọle mọ́: OLUWA si ti wi fun mi pe, Iwọ ki yio gòke Jordani yi mọ́.


Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, gẹgẹ bi ohun gbogbo ti OLUWA ti wi fun Mose; Joṣua si fi i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi ipín wọn nipa ẹ̀ya wọn. Ilẹ na si simi lọwọ ogun.


JOṢUA si gbó o si pọ̀ li ọjọ́; OLUWA si wi fun u pe, Iwọ gbó, iwọ si pọ̀ li ọjọ́, ilẹ pipọ̀pipọ si kù lati gbà.


OLUWA si fun wọn ni isimi yiká kiri, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o bura fun awọn baba wọn: kò si sí ọkunrin kan ninu gbogbo awọn ọtá wọn ti o duro niwaju wọn; OLUWA fi gbogbo awọn ọtá wọn lé wọn lọwọ.


Njẹ nisisiyi OLUWA Ọlọrun nyin ti fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: njẹ nisisiyi ẹ pada, ki ẹ si lọ sinu agọ́ nyin, ati si ilẹ-iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA ti fun nyin ni ìha keji Jordani.


Si wõ, nisisiyi, ọba na nrìn niwaju nyin: emi si ti di arugbo, mo si hewu; si wõ, awọn ọmọ mi si mbẹ lọdọ nyin: emi ti nrìn niwaju nyìn lati igba ewe mi wá titi o fi di oni yi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan