Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 22:9 - Bibeli Mimọ

9 Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse si pada, nwọn si lọ kuro lọdọ awọn ọmọ Israeli lati Ṣilo, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, lati lọ si ilẹ Gileadi, si ilẹ iní wọn, eyiti nwọn ti gbà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA lati ọwọ́ Mose wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ọmọ Israẹli yòókù sílẹ̀ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì pada lọ sí ilẹ̀ Gileadi tí í ṣe ilẹ̀ tiwọn tí wọ́n pín fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Báyìí ni àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ará Israẹli sílẹ̀ ní Ṣilo ní Kenaani láti padà sí Gileadi, ilẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 22:9
19 Iomraidhean Croise  

On si fi i jọba lori Gileadi, ati lori awọn ọmọ Aṣuri, ati lori Jesreeli, ati lori Efraimu, ati lori Benjamini, ati lori gbogbo Israeli.


Ati niha ariwa, o tẹ̀do lọ titi de ati-wọ̀ aginju lati odò Eufrate; nitoriti ẹran ọ̀sin wọn pọ̀ si i ni ilẹ Gileadi.


Ti emi ni Gileadi, ti emi ni Manasse; Efraimu pẹlu li agbara ori mi; Juda li olofin mi;


NJẸ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ní ọ̀pọlọpọ ohunọ̀sin: nwọn si ri ilẹ Jaseri, ati ilẹ Gileadi, si kiyesi i, ibẹ̀ na, ibi ohunọ̀sin ni;


Mose si wi fun wọn pe, Bi ẹnyin o ba ṣe eyi; bi ẹnyin o ba di ihamọra niwaju OLUWA lọ si ogun,


Ti a o si fi ṣẹ́ ilẹ na niwaju OLUWA: lẹhin na li ẹnyin o pada, ẹnyin o si jẹ́ àlailẹṣẹ niwaju OLUWA, ati niwaju Israeli; ilẹ yi yio si ma jẹ́ iní nyin niwaju OLUWA.


Awọn ọmọ wẹ́wẹ wa, ati awọn aya wa, agbo-ẹran wa, ati gbogbo ohunọsìn wa yio wà nibẹ̀ ni ilu Gileadi:


Mose si wi fun wọn pe, Bi awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni yio ba bá nyin gòke Jordani lọ, olukuluku ni ihamọra fun ogun, niwaju OLUWA, ti a si ṣẹ́ ilẹ na niwaju nyin; njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ Gileadi fun wọn ni iní:


Mo si fun nyin li aṣẹ ni ìgbana, wipe, OLUWA Ọlọrun nyin ti fi ilẹ yi fun nyin lati ní i: ẹnyin o si kọja si ìha keji ni ihamọra ogun niwaju awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Israeli, gbogbo awọn akọni ọkunrin.


Titi OLUWA o fi fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti fi fun ẹnyin, ati titi awọn pẹlu yio fi ní ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun wọn loke Jordani: nigbana li ẹnyin o pada, olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀, ti mo ti fi fun nyin.


MOSE si gòke lati pẹtẹlẹ̀ Moabu lọ si òke Nebo, si ori Pisga, ti o dojukọ Jeriko. OLUWA si fi gbogbo ilẹ Gileadi dé Dani hàn a;


Ati Gileadi, ati àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati gbogbo òke Hermoni, ati gbogbo Baṣani dé Saleka;


Àla wọn bẹ̀rẹ ni Jaseri, ati gbogbo ilu Gileadi, ati àbọ ilẹ awọn ọmọ Ammoni, titi dé Aroeri ti mbẹ niwaju Rabba;


Ati àbọ Gileadi, ati Aṣtarotu, ati Edrei, ilu ilẹ-ọba Ogu ni Baṣani, jẹ́ ti awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ani ti àbọ awọn ọmọ Makiri, gẹgẹ bi idile wọn.


Nigbati nwọn si dé eti Jordani, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse mọ pẹpẹ kan lẹba Jordani, pẹpẹ ti o tobi lati wò.


NIGBANA ni gbogbo awọn ọmọ Israeli jade lọ, ijọ awọn enia si wọjọ pọ̀ bi ọkunrin kan, lati Dani lọ titi o fi dé Beeri-ṣeba, pẹlu ilẹ Gileadi, si ọdọ OLUWA ni Mispa.


Gileadi joko loke odò Jordani: ẽṣe ti Dani fi joko ninu ọkọ̀? Aṣeri joko leti okun, o si ngbé ebute rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan