Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 21:1 - Bibeli Mimọ

1 NIGBANA ni awọn olori awọn baba awọn ọmọ Lefi sunmọ Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn náà àwọn olórí ìdílé ninu ẹ̀yà Lefi wá sí ọ̀dọ̀ Eleasari alufaa, ati sí ọ̀dọ̀ Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn olórí ìdílé ní gbogbo ẹ̀yà Israẹli,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Báyìí ni olórí ìdílé àwọn ọmọ Lefi lọ bá Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti olórí ẹ̀yà àwọn ìdílé ẹ̀yà Israẹli

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 21:1
9 Iomraidhean Croise  

Ifibú ni ibinu wọn, nitori ti o rorò; ati ikannu wọn, nitori ti o ní ìka: emi o pin wọn ni Jakobu, emi o si tú wọn ká ni Israeli.


Wọnyi li olori ile baba wọn: awọn ọmọ Reubeni akọ́bi Israeli; Hanoku, ati Pallu, Hesroni, ati Karmi: wọnyi ni idile Reubeni.


Eleasari ọmọ Aaroni si fẹ́ ọkan ninu awọn ọmọbinrin Putieli li aya; on si bi Finehasi fun u: wọnyi li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi ni idile wọn.


OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe,


Ati ilu ti ẹnyin o fi fun wọn, ki o jẹ́ ninu ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli, lọwọ ẹniti o ní pupọ̀ lí ẹnyin o gbà pupọ̀; ṣugbọn lọwọ ẹniti o ní diẹ li ẹnyin o gbà diẹ: ki olukuluku ki o fi ninu ilu rẹ̀ fun awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ilẹ-iní rẹ̀ ti o ní.


WỌNYI si ni ilẹ-iní ti awọn ọmọ Israeli gbà ni iní ni ilẹ Kenaani, ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli pín fun wọn,


Nwọn si wá siwaju Eleasari alufa, ati siwaju Joṣua ọmọ Nuni, ati siwaju awọn olori, wipe, OLUWA fi aṣẹ fun Mose lati fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin wa: nitorina o fi ilẹ-iní fun wọn lãrin awọn arakunrin baba wọn, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA.


Wọnyi ni ilẹ-iní ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli fi keké pín ni ilẹ-iní ni Ṣilo niwaju OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ ajọ. Bẹ̃ni nwọn pari pipín ilẹ na.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan