Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 20:3 - Bibeli Mimọ

3 Ki apania ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan li aimọ̀ ki o le salọ sibẹ̀: nwọn o si jẹ́ àbo fun nyin lọwọ olugbẹsan ẹ̀jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sibẹ. Ibẹ̀ ni yóo jẹ́ ibi ààbò fun yín tí ọwọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kò fi ní máa tẹ̀ yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 kí ẹni tí ó bá ṣèèṣì pa ènìyàn tàbí tí ó bá pa ènìyàn láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ lè sálọ sí ibẹ̀, fún ààbò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 20:3
8 Iomraidhean Croise  

O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọba ki o ranti Oluwa Ọlọrun rẹ̀, ki olugbẹsan ẹjẹ ki o máṣe ni ipa lati ṣe iparun, ki nwọn ki o má bà pa ọmọ mi; on si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkan ninu irun ori ọmọ rẹ ki yio bọ́ silẹ,


Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkàn kan ba fi aimọ̀ sẹ̀ si ọkan ninu ofin OLUWA, li ohun ti kò yẹ ni ṣiṣe, ti o si ṣẹ̀ si ọkan ninu wọn:


Nwọn o si jasi ilu àbo kuro lọwọ agbẹsan; ki ẹniti o pa enia ki o má ba kú titi yio fi duro niwaju ijọ awọn enia ni idajọ.


Agbẹsan ẹ̀jẹ tikalarẹ̀ ni ki o pa apania na: nigbati o ba bá a, ki o pa a.


Ṣugbọn bi o ba fi nkan gún u lojiji laiṣe ọtá, tabi ti o sọ ohunkohun lù u laiba dè e,


Pe, nipa ohun aileyipada meji, ninu eyiti ko le ṣe iṣe fun Ọlọrun lati ṣeke, ki awa ti o ti sá sabẹ ãbo le ni ìṣírí ti o daju lati dì ireti ti a gbé kalẹ niwaju wa mu:


Wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ yàn ilu àbo fun ara nyin, ti mo ti sọ fun nyin lati ọwọ́ Mose wa:


On o si salọ si ọkan ninu ilu wọnni, yio si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na, yio si rò ẹjọ́ rẹ̀ li etí awọn àgba ilu na, nwọn o si gbà a sọdọ sinu ilu na, nwọn o si fun u ni ibi kan, ki o le ma bá wọn gbé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan