Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 2:6 - Bibeli Mimọ

6 Ṣugbọn o ti mú wọn gòke àja ile, o si fi poroporo ọ̀gbọ ti o ti tòjọ soke àja bò wọn mọlẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Ṣugbọn ó ti kó wọn gun orí òrùlé rẹ̀, ó sì ti fi wọ́n pamọ́ sáàrin pòpórò igi ọ̀gbọ̀ tí ó tò jọ sibẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 (Ṣùgbọ́n ó ti mú wọn gòkè àjà ó sì fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ pòròpòrò ọkà tó tò jọ sí orí àjà.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 2:6
17 Iomraidhean Croise  

O si ṣe, ni igbà aṣalẹ kan, Dafidi si dide ni ibusùn rẹ̀, o si nrìn lori orule ile ọba, lati ori orule na li o si ri obinrin kan ti o nwẹ̀ ara rẹ̀; obinrin na si ṣe arẹwa jọjọ lati wò.


Obinrin rẹ̀ si mu nkan o fi bo kanga na, o si sa agbado sori rẹ̀; a kò si mọ̀.


A kò ha sọ fun oluwa mi, ohun ti mo ṣe nigbati Jesebeli pa awọn woli Oluwa, bi mo ti pa ọgọrun enia mọ ninu awọn woli Oluwa li aradọta ninu ihò-okuta, ti mo si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn?


O si ṣe, nigbati Jesebeli ke awọn woli Oluwa kuro, ni Obadiah mu ọgọrun woli, o si fi wọn pamọ li aradọta ni iho okuta; o si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn.


Ṣugbọn Jehoṣeba ọmọbinrin Joramu ọba, arabinrin Ahasiah, mu Joaṣi ọmọ Ahasiah, o si ji i gbé kuro ninu awọn ọmọ ọba ti a pa; nwọn si pa a mọ́ ninu iyẹ̀wu kuro lọdọ Ataliah, on, ati alagbatọ́ rẹ̀, ti a kò si fi pa a.


Obinrin na si yún, o si bi ọmọkunrin kan: nigbati o si ri i pe, o ṣe ọmọ didara, o pa a mọ́ li oṣù mẹta.


Ṣugbọn ọba paṣẹ fun Jerameeli, ọmọ Hameleki, ati Seraiah, ọmọ Asraeli, ati Ṣelemiah, ọmọ Abdeeli, lati mu Baruku akọwe, ati Jeremiah woli: ṣugbọn Oluwa fi wọn pamọ.


Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o maṣe sọkalẹ wá imu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀:


Nigbati iwọ ba kọ ile titun kan, ki iwọ ki o ṣe igbáti si orule rẹ, ki iwọ o má ba mú ẹ̀jẹ wá sara ile rẹ, bi ẹnikan ba ti ibẹ̀ ṣubu.


Nitori ẹnyin ti kú, a si fi ìye nyin pamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun.


Nipa igbagbọ́ ni awọn obi Mose pa a mọ́ fun oṣu mẹta nigbati a bí i, nitoriti nwọn ri i ni arẹwa ọmọ; nwọn kò si bẹ̀ru aṣẹ ọba.


Gẹgẹ bẹ̃ pẹlu kí a ha dá Rahabu panṣaga lare nipa iṣẹ, nigbati o gbà awọn onṣẹ, ti o si rán wọn jade gba ọ̀na miran?


O si ṣe li akokò ati tì ilẹkun ẹnubode, nigbati ilẹ ṣú, awọn ọkunrin na si jade lọ: ibi ti awọn ọkunrin na gbé lọ, emi kò mọ̀: ẹ lepa wọn kánkán; nitori ẹnyin o bá wọn.


Awọn ọkunrin na lepa wọn li ọ̀na ti o lọ dé iwọ̀do Jordani: bi awọn ti nlepa wọn si ti jade lọ, nwọn tì ilẹkun ẹnubode.


Ki nwọn ki o tó dubulẹ, o gòke tọ̀ wọn lọ loke àja;


Joṣua si gbà Rahabu panṣaga là, ati ara ile baba rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní; o si joko lãrin Israeli titi di oni-oloni; nitoriti o pa awọn onṣẹ mọ́ ti Joṣua rán lọ ṣamí Jeriko.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan